7 Ati pe Jakobu gbọ́ ti baba ati ti iya rẹ̀, ti o si lọ si Padan-aramu:
8 Nigbati Esau ri pe awọn ọmọbinrin Kenaani kò wù Isaaki baba rẹ̀;
9 Nigbana ni Esau tọ̀ Iṣmaeli lọ, o si fẹ́ Mahalati ọmọbinrin Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu, arabinrin Nebajotu, kún awọn obinrin ti o ni.
10 Jakobu si jade kuro lati Beer-ṣeba lọ, o si lọ si ìha Harani.
11 O si de ibi kan, o duro nibẹ̀ li oru na, nitori õrùn wọ̀; o si mu ninu okuta ibẹ̀ na, o fi ṣe irọri rẹ̀, o si sùn nibẹ̀ na.
12 O si lá alá, si kiyesi i, a gbé àkasọ kan duro lori ilẹ, ori rẹ̀ si de oke ọrun: si kiyesi i, awọn angeli Ọlọrun ngoke, nwọn si nsọkalẹ lori rẹ̀.
13 Si kiyesi i, OLUWA duro loke rẹ̀, o si wi pe, Emi li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu baba rẹ, ati Ọlọrun Isaaki; ilẹ ti iwọ dubulẹ le nì, iwọ li emi o fi fun, ati fun irú-ọmọ rẹ.