9 Nigbati o si mba wọn sọ̀rọ lọwọ, Rakeli de pẹlu awọn agutan baba rẹ̀: on li o sa nṣọ́ wọn.
10 O si ṣe, nigbati Jakobu ri Rakeli, ọmọbinrin Labani, arakunrin iya rẹ̀, ati agutan Labani, arakunrin iya rẹ̀, ni Jakobu si sunmọ ibẹ̀, o si yí okuta kuro li ẹnu kanga, o si fi omi fun gbogbo agbo-ẹran Labani, arakunrin iya rẹ̀.
11 Jakobu si fi ẹnu kò Rakeli li ẹnu, o si gbé ohùn rẹ̀ soke, o sọkun.
12 Jakobu si wi fun Rakeli pe arakunrin baba rẹ̀ li on, ati pe, ọmọ Rebeka li on: ọmọbinrin na si sure o si sọ fun baba rẹ̀.
13 O si ṣe ti Labani gburó Jakobu, ọmọ arabinrin rẹ̀, o sure lọ ipade rẹ̀, o si gbá a mú, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si mu u wá si ile rẹ̀. On si ròhin gbogbo nkan wọnni fun Labani.
14 Labani si wi fun u pe, egungun on ẹran-ara mi ni iwọ iṣe nitõtọ. O si bá a joko ni ìwọn oṣù kan.
15 Labani si wi fun Jakobu pe, Iwọ o ha ma sìn mi li asan bi, nitoriti iwọ iṣe arakunrin mi? elo li owo iṣẹ rẹ, wi fun mi?