17 O si wi fun Adamu pe, Nitoriti iwọ gbà ohùn aya rẹ gbọ́, ti iwọ si jẹ ninu eso igi na, ninu eyiti mo ti paṣẹ fun ọ pe, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀; a fi ilẹ bú nitori rẹ; ni ipọnju ni iwọ o ma jẹ ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo;
18 Ẹgún on oṣuṣu ni yio ma hù jade fun ọ, iwọ o si ma jẹ eweko igbẹ:
19 Li õgùn oju rẹ ni iwọ o ma jẹun, titi iwọ o fi pada si ilẹ; nitori inu rẹ̀ li a ti mu ọ wá, erupẹ sa ni iwọ, iwọ o si pada di erupẹ.
20 Adamu si pè orukọ aya rẹ̀ ni Efa; nitori on ni iṣe iya alãye gbogbo.
21 Ati fun Adamu ati fun aya rẹ̀ li OLUWA Ọlọrun da ẹwu awọ, o si fi wọ̀ wọn.
22 OLUWA Ọlọrun si wipe, Wò o, ọkunrin na dabi ọkan ninu wa lati mọ̀ rere ati bururu: njẹ nisisiyi ki o má ba nà ọwọ́ rẹ̀ ki o si mu ninu eso igi ìye pẹlu, ki o si jẹ, ki o si yè titi lai;
23 Nitorina OLUWA Ọlọrun lé e jade kuro ninu ọgbà Edeni, lati ma ro ilẹ ninu eyiti a ti mu u jade wá.