14 Rakeli ati Lea si dahùn nwọn si wi fun u pe, Ipín, tabi ogún kan ha tun kù fun wa mọ́ ni ile baba wa?
15 Alejò ki on nkà wa si? nitori ti o ti tà wa; o si ti mù owo wa jẹ gúdu-gudu.
16 Nitori ọrọ̀ gbogbo ti Ọlọrun ti gbà lọwọ baba wa, eyinì ni ti wa, ati ti awọn ọmọ wa: njẹ nisisiyi ohunkohun ti Ọlọrun ba sọ fun ọ, on ni ki o ṣe.
17 Nigbana ni Jakobu dide, o si gbé awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn aya rẹ̀ gùn ibakasiẹ.
18 O si kó gbogbo ẹran rẹ̀ lọ, ati gbogbo ẹrù ti o ní, ẹran ti o ní fun ara rẹ̀, ti o ní ni Padan-aramu, lati ma tọ̀ Isaaki baba rẹ̀ lọ ni ilẹ Kenaani.
19 Labani si lọ irẹrun agutan rẹ̀: Rakeli si ti jí awọn ere baba rẹ̀ lọ.
20 Jakobu si tàn Labani ara Siria jẹ, niti pe kò wi fun u ti o fi salọ.