18 O si kó gbogbo ẹran rẹ̀ lọ, ati gbogbo ẹrù ti o ní, ẹran ti o ní fun ara rẹ̀, ti o ní ni Padan-aramu, lati ma tọ̀ Isaaki baba rẹ̀ lọ ni ilẹ Kenaani.
19 Labani si lọ irẹrun agutan rẹ̀: Rakeli si ti jí awọn ere baba rẹ̀ lọ.
20 Jakobu si tàn Labani ara Siria jẹ, niti pe kò wi fun u ti o fi salọ.
21 Bẹ̃li o kó ohun gbogbo ti o ní salọ: o si dide, o si kọja odò, o si kọju rẹ̀ si oke Gileadi.
22 A si wi fun Labani ni ijọ́ kẹta pe, Jakobu salọ.
23 O si mú awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu rẹ̀, o si lepa rẹ̀ ni ìrin ijọ́ meje: o si bá a li oke Gileadi.
24 Ọlọrun si tọ̀ Labani, ara Siria wá li oru li oju-alá, o si wi fun u pe, Kiyesi ara rẹ, ki iwọ ki o máṣe bá Jakobu sọ rere tabi buburu.