30 Ati nisisiyi, iwọ kò le ṣe ailọ, nitori ti ọkàn rẹ fà gidigidi si ile baba rẹ, ṣugbọn ẽhaṣe ti iwọ fi jí awọn oriṣa mi lọ?
31 Jakobu si dahùn o si wi fun Labani pe, Nitori ti mo bẹ̀ru ni: nitori ti mo wipe, iwọ le fi agbara gbà awọn ọmọbinrin rẹ lọwọ mi.
32 Lọwọ ẹnikẹni ti iwọ ba ri awọn oriṣa rẹ ki o máṣe wà lãye: li oju awọn arakunrin wa wọnyi, wá ohun ti iṣe tirẹ lọdọ mi, ki o si mú u si ọdọ rẹ. Jakobu kò sa mọ̀ pe Rakeli ti jí wọn.
33 Labani si wọ̀ inu agọ́ Jakobu lọ, ati inu agọ́ Lea, ati inu agọ́ awọn iranṣẹbinrin mejeji; ṣugbọn kò ri wọn. Nigbana li o jade kuro ninu agọ́ Lea, o si wọ̀ inu agọ́ Rakeli lọ.
34 Rakeli si gbé awọn ere na, o si fi wọn sinu gãri ibakasiẹ, o si joko le wọn. Labani si wá gbogbo agọ́ ṣugbọn kò ri wọn.
35 O si wi fun baba rẹ̀ pe, Oluwa mi, máṣe jẹ ki o bi ọ ninu nitori ti emi kò le dide niwaju rẹ; nitori ti iṣe obinrin mbẹ lara mi. O si wá agọ́ kiri, ṣugbọn kò ri awọn ere na.
36 Inu si bi Jakobu, o si bá Labani sọ̀: Jakobu si dahùn o wi fun Labani pe, Kini irekọja mi? kili ẹ̀ṣẹ mi ti iwọ fi lepa mi wìriwiri bẹ̃?