33 Labani si wọ̀ inu agọ́ Jakobu lọ, ati inu agọ́ Lea, ati inu agọ́ awọn iranṣẹbinrin mejeji; ṣugbọn kò ri wọn. Nigbana li o jade kuro ninu agọ́ Lea, o si wọ̀ inu agọ́ Rakeli lọ.
34 Rakeli si gbé awọn ere na, o si fi wọn sinu gãri ibakasiẹ, o si joko le wọn. Labani si wá gbogbo agọ́ ṣugbọn kò ri wọn.
35 O si wi fun baba rẹ̀ pe, Oluwa mi, máṣe jẹ ki o bi ọ ninu nitori ti emi kò le dide niwaju rẹ; nitori ti iṣe obinrin mbẹ lara mi. O si wá agọ́ kiri, ṣugbọn kò ri awọn ere na.
36 Inu si bi Jakobu, o si bá Labani sọ̀: Jakobu si dahùn o wi fun Labani pe, Kini irekọja mi? kili ẹ̀ṣẹ mi ti iwọ fi lepa mi wìriwiri bẹ̃?
37 Njẹ bi iwọ ti tú ẹrù mi gbogbo, kili iwọ ri ninu gbogbo nkan ile rẹ? gbé e kalẹ nihinyi niwaju awọn arakunrin rẹ, ki nwọn ki o le ṣe idajọ rẹ̀ fun awa mejeji.
38 Ogún ọdún yi ni mo ti wà lọdọ rẹ; agutan rẹ ati ewurẹ rẹ kò sọnù, agbo ọwọ́-ẹran rẹ li emi kò si pajẹ.
39 Eyiti ẹranko fàya emi kò mú u fun ọ wá; emi li o gbà òfo rẹ̀; li ọwọ́ mi ni iwọ bère rẹ̀, a ba jí i li ọsán, a ba jí i li oru.