10 Ọlọrun si wi fun u pe, Jakobu li orukọ rẹ: a ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli li orukọ rẹ yio ma jẹ́: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Israeli.
11 Ọlọrun si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare: ma bisi i, si ma rẹ̀; orilẹ-ède, ati ẹgbẹ-ẹgbẹ orilẹ-ède ni yio ti ọdọ rẹ wá, awọn ọba yio si ti inu rẹ jade wá;
12 Ati ilẹ ti mo ti fi fun Abrahamu ati Isaaki, iwọ li emi o fi fun, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ li emi o fi ilẹ na fun.
13 Ọlọrun si lọ soke kuro lọdọ rẹ̀ ni ibi ti o gbé mbá a sọ̀rọ.
14 Jakobu si fi ọwọ̀n kan lelẹ ni ibi ti o gbé bá a sọ̀rọ, ani ọwọ̀n okuta: o si ta ọrẹ ohun mimu si ori rẹ̀, o si ta oróro si ori rẹ̀.
15 Jakobu si sọ orukọ ibi ti Ọlọrun gbé bá a sọ̀rọ ni Beteli.
16 Nwọn si rìn lati Beteli lọ; o si kù diẹ ki nwọn ki o dé Efrati: ibi si tẹ̀ Rakeli: o si ṣoro jọjọ fun u.