19 Wọnyi li awọn ọmọ Esau, eyini ni Edomu, wọnyi si li awọn olori wọn.
20 Wọnyi li awọn ọmọ Seiri, enia Hori, ti o tẹ̀dó ni ilẹ na; Lotani, ati Ṣobali, ati Sibeoni, ati Ana,
21 Ati Diṣoni, ati Eseri, ati Diṣani: wọnyi li awọn olori enia Hori, awọn ọmọ Seiri ni ilẹ Edomu.
22 Ati awọn ọmọ Lotani ni Hori ati Hemamu: arabinrin Lotani si ni Timna.
23 Ati awọn ọmọ Ṣobali ni wọnyi; Alfani, ati Mahanati, ati Ebali, Sefo, ati Onamu.
24 Wọnyi si li awọn ọmọ Sibeoni; ati Aja on Ana: eyi ni Ana ti o ri awọn isun omi gbigbona ni ijù, bi o ti mbọ́ awọn kẹtẹkẹtẹ Sibeoni baba rẹ̀.
25 Wọnyi si li awọn ọmọ Ana; Disoni ati Aholibama, ọmọbinrin Ana.