2 Esau fẹ́ awọn aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Kenaani; Ada, ọmọbinrin Eloni, enia Hitti, ati Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, ara Hiffi;
3 Ati Baṣemati, ọmọbinrin Iṣmaeli, arabinrin Nebajotu.
4 Ada si bí Elifasi fun Esau; Baṣemati si bí Reueli;
5 Aholibama si bí Jeuṣi, ati Jaalamu, ati Kora: awọn wọnyi li ọmọkunrin Esau, ti a bí fun u ni ilẹ Kenaani.
6 Esau si mú awọn aya rẹ̀, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn enia ile rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati gbogbo ohun-ọ̀sin, ati ohun iní gbogbo ti o ní ni ilẹ Kenaani; o si lọ si ilẹ kan kuro niwaju Jakobu arakunrin rẹ̀.
7 Nitori ti ọrọ̀ wọn pọ̀ jù ki nwọn ki o gbé pọ̀ lọ; ilẹ ti nwọn si ṣe atipo si kò le gbà wọn, nitori ohun-ọ̀sin wọn.
8 Bẹ̃ni Esau tẹ̀dó li oke Seiri: Esau ni Edomu.