28 Awọn ọmọ Diṣani ni wọnyi; Usi ati Arani.
29 Wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Hori wá; Lotani olori, Ṣobali olori, Sibeoni olori, Ana olori,
30 Diṣoni olori, Eseri olori, Diṣani olori; wọnyi li awọn olori awọn enia Hori, ninu awọn olori wọn ni ilẹ Seiri.
31 Wọnyi si li awọn ọba ti o jẹ ni ilẹ Edomu, ki ọba kan ki o to jọba lori awọn ọmọ Israeli.
32 Bela ti iṣe ọmọ Beori si jọba ni Edomu: orukọ ilu rẹ̀ a si ma jẹ́ Dinhaba.
33 Bela si kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra si jọba ni ipò rẹ̀.
34 Jobabu si kú, Huṣamu ti ilẹ Temani si jọba ni ipò rẹ̀.