7 Nitori ti ọrọ̀ wọn pọ̀ jù ki nwọn ki o gbé pọ̀ lọ; ilẹ ti nwọn si ṣe atipo si kò le gbà wọn, nitori ohun-ọ̀sin wọn.
8 Bẹ̃ni Esau tẹ̀dó li oke Seiri: Esau ni Edomu.
9 Wọnyi si ni iran Esau, baba awọn ara Edomu, li oke Seiri:
10 Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Esau; Elifasi, ọmọ Ada, aya Esau, Rueli, ọmọ Baṣemati, aya Esau.
11 Ati awọn ọmọ Elifasi ni Temani, Omari, Sefo, ati Gatamu, ati Kenasi.
12 Timna li o si ṣe àle Elifasi, ọmọ Esau; on si bí Amaleki fun Elifasi; wọnyi si li awọn ọmọ Ada, aya Esau.
13 Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli; Nahati, ati Sera, Ṣamma, ati Misa: awọn wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau.