1 A SI mú Josefu sọkalẹ wá si Egipti; Potifari, ijoye Farao kan, olori ẹṣọ́, ara Egipti, si rà a lọwọ awọn ara Iṣmaeli ti o mú u sọkalẹ wá sibẹ̀.
2 OLUWA si wà pẹlu Josefu, o si ṣe alasiki enia; o si wà ni ile oluwa rẹ̀ ara Egipti na.
3 Oluwa rẹ̀ si ri pe OLUWA pẹlu rẹ̀, ati pe, OLUWA mu ohun gbogbo ti o ṣe dara li ọwọ́ rẹ̀.
4 Josefu si ri ojurere li oju rẹ̀, on si nsìn i: o si fi i jẹ́ olori ile rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní on li o fi lé e lọwọ.
5 O si ṣe lati ìgba ti o ti fi Josefu jẹ́ olori ile rẹ̀, ati olori ohun gbogbo ti o ní, ni OLUWA busi ile ara Egipti na nitori Josefu: ibukún OLUWA si wà lara ohun gbogbo ti o ní ni ile ati li oko.
6 O si fi ohun gbogbo ti o ní si ọwọ́ Josefu; kò si mọ̀ ohun ti on ní bikoṣe onjẹ ti o njẹ. Josefu si ṣe ẹni daradara ati arẹwà enia.