23 Si kiyesi i, ṣiri ọkà meje rirẹ̀, ti o si fori, ati ti ẹfũfu ìla-õrùn rẹ̀ dànu, o rú jade lẹhin wọn:
24 Awọn ṣiri ti o fori si mú awọn ṣiri rere meje nì jẹ; mo si rọ́ ọ fun awọn amoye; ṣugbọn kò sí ẹniti o le sọ ọ fun mi.
25 Josefu si wi fun Farao pe, Ọkan li alá Farao: Ọlọrun ti fi ohun ti on mbọ̀wá iṣe hàn fun Farao.
26 Awọn abo-malu daradara meje nì, ọdún meje ni: ati ṣiri daradara meje nì, ọdún meje ni: ọkan li alá na.
27 Ati awọn abo-malu meje nì ti o rù ti o si buru ni wiwò ti nwọn jade soke lẹhin wọn, ọdún meje ni; ati ṣiri ọkà meje ti o fori nì, ti ẹfũfu ìla-õrùn rẹ̀ dànu nì, ọdún meje ìyan ni yio jasi.
28 Eyi li ohun ti mo ti wi fun Farao pe, ohun ti Ọlọrun mbọ̀wá iṣe, o ti fihàn fun Farao.
29 Kiyesi i, ọdún meje ọ̀pọ mbọ̀ já gbogbo ilẹ Egipti: