13 Nwọn si wipe, Arakunrin mejila li awa iranṣẹ rẹ, ọmọ ẹnikan na ni ilẹ Kenaani: si wò o, eyi abikẹhin si wà lọdọ baba wa loni-oloni, ọkan kò si sí.
14 Josefu si wi fun wọn pe, On na li eyiti mo wi fun nyin pe, Amí li ẹnyin:
15 Eyi bayi li a o fi ridi nyin, nipa ẹmi Farao bi ẹnyin o ti lọ nihin, bikoṣepe arakunrin abikẹhin nyin wá ihinyi.
16 Ẹ rán ẹnikan ninu nyin, ki o si mú arakunrin nyin wá, a o si pa nyin mọ́ ninu túbu, ki a le ridi ọ̀rọ nyin, bi otitọ wà ninu nyin: bikoṣe bẹ̃, ẹmi Farao bi amí ki ẹnyin iṣe.
17 O si kó gbogbo wọn pọ̀ sinu túbu ni ijọ́ mẹta.
18 Josefu si wi fun wọn ni ijọ́ kẹta pe, Ẹ ṣe eyi ki ẹ si yè; nitori emi bẹ̀ru Ọlọrun.
19 Bi ẹnyin ba ṣe olõtọ enia, ki a mú ọkan ninu awọn arakunrin nyin dè ni ile túbu nyin: ẹ lọ, ẹ mú ọkà lọ nitori ìyan ile nyin.