18 Josefu si wi fun wọn ni ijọ́ kẹta pe, Ẹ ṣe eyi ki ẹ si yè; nitori emi bẹ̀ru Ọlọrun.
19 Bi ẹnyin ba ṣe olõtọ enia, ki a mú ọkan ninu awọn arakunrin nyin dè ni ile túbu nyin: ẹ lọ, ẹ mú ọkà lọ nitori ìyan ile nyin.
20 Ṣugbọn ẹ mú arakunrin nyin abikẹhin fun mi wá; bẹ̃li a o si mọ̀ ọ̀rọ nyin li otitọ, ẹ ki yio si kú. Nwọn si ṣe bẹ̃.
21 Nwọn si wi fun ara wọn pe, Awa jẹbi nitõtọ nipa ti arakunrin wa, niti pe, a ri àrokan ọkàn rẹ̀, nigbati o bẹ̀ wa, awa kò si fẹ́ igbọ́; nitorina ni iyọnu yi ṣe bá wa.
22 Reubeni si da wọn li ohùn pe, Emi kò wi fun nyin pe, Ẹ máṣe ṣẹ̀ si ọmọde na; ẹ kò si fẹ̀ igbọ́? si wò o, nisisiyi, a mbère ẹ̀jẹ rẹ̀.
23 Nwọn kò si mọ̀ pe Josefu gbède wọn; nitori gbedegbẹyọ li o fi mba wọn sọ̀rọ.
24 O si yipada kuro lọdọ wọn, o si sọkun; o si tun pada tọ̀ wọn wá, o si bá wọn sọ̀rọ, o si mú Ṣimeoni ninu wọn, o si dè e li oju wọn.