1 ÌYAN na si mú ni ilẹ na gidigidi.
2 O si ṣe, nigbati nwọn jẹ ọkà ti nwọn ti múbọ̀ Egipti wá tán, baba wọn wi fun wọn pe, Ẹ tun lọ irà onjẹ diẹ fun wa wá.
3 Judah si wi fun u pe, ọkunrin na tẹnumọ́ ọ gidigidi fun wa pe, Ẹnyin kò gbọdọ ri oju mi, bikoṣepe arakunrin nyin ba pẹlu nyin.
4 Bi iwọ o ba rán arakunrin wa pẹlu wa, awa o sọkalẹ lọ lati rà onjẹ fun ọ:
5 Ṣugbọn bi iwọ ki yio ba rán a, awa ki yio sọkalẹ lọ: nitoriti ọkunrin na wi fun wa pe, Ẹnyin ki yio ri oju mi, bikoṣe arakunrin nyin ba pẹlu nyin.
6 Israeli si wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi hùwa buburu bẹ̃ si mi, ti ẹnyin fi wi fun ọkunrin na pe, ẹnyin ní arakunrin kan pẹlu?
7 Nwọn si wipe, ọkunrin na bère timọtimọ niti awa tikara wa, ati niti ibatan wa, wipe, Baba nyin wà sibẹ̀? ẹnyin li arakunrin miran? awa si wi fun u bi ọ̀rọ wọnyi: awa o ti ṣe le mọ̀ daju pe yio wipe, Mú arakunrin nyin sọkalẹ wá?