17 On si wipe, Ki a má ri pe emi o ṣe bẹ̃: ṣugbọn ọkunrin na li ọwọ́ ẹniti a ri ago na, on ni yio ṣe ẹrú mi; bi o ṣe ti ẹnyin, ẹ goke tọ̀ baba nyin lọ li alafia.
18 Nigbana ni Judah sunmọ ọdọ rẹ̀, o si wipe, Oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ ki o sọ gbolohùn ọ̀rọ kan li eti oluwa mi, ki o máṣe binu si iranṣẹ rẹ; bi Farao tikalarẹ̀ ni iwọ sá ri.
19 Oluwa mi bère lọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, wipe, Ẹnyin ní baba, tabi arakunrin bi?
20 Awa si wi fun oluwa mi pe, Awa ní baba, arugbo, ati ọmọ kan li ogbologbo rẹ̀, abikẹhin; arakunrin rẹ̀ si kú, on nikanṣoṣo li o si kù li ọmọ iya rẹ̀, baba rẹ̀ si fẹ́ ẹ.
21 Iwọ si wi fun awọn iranṣẹ rẹ pe, Mú u sọkalẹ tọ̀ mi wá, ki emi ki o le fi oju mi kàn a.
22 Awa si wi fun oluwa mi pe, Ọdọmọde na kò le fi baba rẹ̀ silẹ: nitoripe bi o ba fi i silẹ, baba rẹ̀ yio kú.
23 Iwọ si wi fun awọn iranṣẹ rẹ pe, Ayaṣebi arakunrin nyin abikẹhin ba bá nyin sọkalẹ wá, ẹnyin ki yio ri oju mi mọ́.