3 Bi ojúmọ si ti mọ́, a si rán awọn ọkunrin na lọ, awọn ati awọn kẹtẹkẹtẹ wọn.
4 Nigbati nwọn si jade kuro ni ilu na, ti nwọn kò si jìna, Josefu wi fun iriju rẹ̀ pe, Dide, lepa awọn ọkunrin na; nigbati iwọ ba si bá wọn, wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi fi buburu san rere?
5 Ninu eyi ki oluwa mi ima mu, eyiti o si fi nmọ̀ran? ẹnyin ṣe buburu li eyiti ẹnyin ṣe yi.
6 O si lé wọn bá, o si sọ ọ̀rọ wọnyi fun wọn.
7 Nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti oluwa mi fi sọ irú ọ̀rọ wọnyi? Ki a má ri pe awọn ọmọ-ọdọ rẹ ṣe bi irú nkan wọnyi.
8 Kiyesi i, owo ti awa ri li ẹnu àpo wa, awa si tun mú pada fun ọ lati ilẹ Kenaani wá: bawo li awa o ṣe jí fadaka tabi wurà ninu ile oluwa rẹ?
9 Lọdọ ẹnikẹni ninu awọn iranṣẹ rẹ ti a ba ri i, ki o kú, ati awa pẹlu ki a di ẹrú oluwa mi.