6 Lati ọdún meji yi ni ìyan ti nmú ni ilẹ: o si tun kù ọdún marun si i, ninu eyiti a ki yio ni itulẹ tabi ikorè.
7 Ọlọrun si rán mi siwaju nyin lati da irú-ọmọ si fun nyin lori ilẹ, ati lati fi ìgbala nla gbà ẹmi nyin là.
8 Njẹ nisisiyi, ki iṣe ẹnyin li o rán mi si ihin, bikoṣe Ọlọrun: o si ti fi mi ṣe baba fun Farao, ati oluwa gbogbo ile rẹ̀, ati alakoso gbogbo ilẹ Egipti.
9 Ẹ yara ki ẹ si goke tọ̀ baba mi lọ, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi ni Josefu ọmọ rẹ wipe, Ọlọrun fi mi jẹ́ oluwa gbogbo Egipti: sọkalẹ tọ̀ mi wá, má si ṣe duro.
10 Iwọ o si joko ni ilẹ Goṣeni, iwọ o si wà leti ọdọ mi, iwọ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ, ati ọwọ-ẹran rẹ, ati ọwọ́-malu rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní.
11 Nibẹ̀ li emi o si ma bọ́ ọ; nitori ọdún ìyan kù marun si i; ki iwọ, ati awọn ara ile rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní, ki o má ba ri ipọnju.
12 Si kiyesi i, oju nyin, ati oju Benjamini arakunrin mi ri pe, ẹnu mi li o nsọ̀rọ fun nyin.