1 NIGBANA ni Josefu wọle, o si sọ fun Farao, o si wipe, Baba mi, ati awọn arakunrin mi ati ọwọ́-ẹran wọn, ati ọwọ́-malu wọn, ati ohun gbogbo ti nwọn ní, nwọn ti ilẹ Kenaani wá; si kiyesi i, nwọn mbẹ ni ilẹ Goṣeni.
2 O si mú marun ninu awọn arakunrin rẹ̀, o si mu wọn duro niwaju Farao.
3 Farao si bi awọn arakunrin rẹ̀ pe, Kini iṣẹ nyin? Nwọn si wi fun Farao pe, Oluṣọ-agutan li awọn iranṣẹ rẹ, ati awa, ati awọn baba wa pẹlu.
4 Nwọn si wi fun Farao pẹlu pe, Nitori ati ṣe atipo ni ilẹ yi li awa ṣe wá; nitori awọn iranṣẹ rẹ kò ní papa-oko tutù fun ọwọ́-ẹran wọn; nitori ti ìyan yi mú gidigidi ni ilẹ Kenaani: njẹ nitorina awa bẹ̀ ọ, jẹ ki awọn iranṣẹ rẹ ki o joko ni ilẹ Goṣeni.
5 Farao si wi fun Josefu pe, Baba rẹ ati awọn arakunrin rẹ tọ̀ ọ wá:
6 Ilẹ Egipti ni yi niwaju rẹ; ninu ãyo ilẹ ni ki o mu baba ati awọn arakunrin rẹ joko; jẹ ki nwọn ki o joko ni ilẹ Goṣeni: bi iwọ ba si mọ̀ ẹnikẹni ti o li ãpọn ninu wọn, njẹ ki iwọ ki o ṣe wọn li olori lori ẹran-ọsin mi.
7 Josefu si mú Jakobu baba rẹ̀ wọle wá, o si mu u duro niwaju Farao: Jakobu si sure fun Farao.