1 O SI ṣe lẹhin nkan wọnyi ni ẹnikan wi fun Josefu pe, Kiyesi i, ara baba rẹ kò dá: o si mú awọn ọmọ rẹ̀ mejeji, Manasse ati Efraimu pẹlu rẹ̀.
2 Ẹnikan si sọ fun Jakobu, o si wipe, Kiyesi i, Josefu ọmọ rẹ tọ̀ ọ wá: Israeli si gbiyanju, o si joko lori akete.
3 Jakobu si wi fun Josefu pe, Ọlọrun Olodumare farahàn mi ni Lusi ni ilẹ Kenaani, o si sure fun mi,
4 O si wi fun mi pe, Kiyesĩ, Emi o mu ọ bisi i, Emi o mu ọ rẹ̀, Emi o si sọ ọ di ọ̀pọlọpọ enia; Emi o si fi ilẹ yi fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iní titi aiye.
5 Njẹ nisisiyi Efraimu ati Manasse, awọn ọmọ rẹ mejeji ti a bí fun ọ ni ilẹ Egipti, ki emi ki o tó tọ̀ ọ wá ni Egipti, ti emi ni nwọn: bi Reubeni on Simeoni, bẹ̃ni nwọn o jẹ́ ti emi.