2 Josefu si paṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn oniṣegun, ki nwọn ki o kùn baba on li ọṣẹ: awọn oniṣegun si kùn Israeli li ọṣẹ.
3 Nwọn si kún ogoji ọjọ́ fun u; nitoripe bẹ̃li a ikún ọjọ́ awọn ti a kùn li ọṣẹ: awọn ara Egipti si ṣọ̀fọ rẹ̀ li ãdọrin ọjọ́.
4 Nigbati ọjọ́ ọ̀fọ rẹ̀ kọja, Josefu sọ fun awọn ara ile Farao pe, Njẹ bi emi ba ri ore-ọfẹ li oju nyin emi bẹ̀ nyin, ẹ wi li eti Farao pe,
5 Baba mi mu mi bura wipe, Kiyesi i, emi kú: ni isà mi ti mo ti wà fun ara mi ni ilẹ Kenaani, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o sin mi. Njẹ nitorina emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o goke lọ, ki emi ki o si lọ isin baba mi, emi o si tun pada wá.
6 Farao si wipe, Goke lọ, ki o si sin okú baba rẹ, gẹgẹ bi o ti mu ọ bura.
7 Josefu si goke lọ lati sin baba rẹ̀: ati gbogbo awọn iranṣẹ Farao, ati awọn àlagba ile rẹ̀, ati gbogbo awọn àlagba ilẹ Egipti si bá a goke lọ.
8 Ati gbogbo awọn ara ile Josefu, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn ara ile baba rẹ̀: kìki awọn ọmọ wẹ́wẹ wọn, ati ọwọ́-ẹran wọn, ati ọwọ́-malu wọn, ni nwọn fi silẹ ni ilẹ Goṣeni.