4 Awọn òmirán wà li aiye li ọjọ́ wọnni; ati lẹhin eyini pẹlu, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wọle tọ̀ awọn ọmọbinrin enia lọ, ti nwọn si bí ọmọ fun wọn, awọn na li o di akọni ti o wà nigbãni, awọn ọkunrin olokikí.
5 Ọlọrun si ri pe ìwabuburu enia di pipọ̀ li aiye, ati pe gbogbo ìro ọkàn rẹ̀ kìki ibi ni lojojumọ.
6 Inu OLUWA si bajẹ nitori ti o dá enia si aiye, o si dùn u de ọkàn rẹ̀.
7 OLUWA si wipe, Emi o pa enia ti mo ti dá run kuro li ori ilẹ; ati enia, ati ẹranko, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun; nitori inu mi bajẹ ti mo ti dá wọn.
8 Ṣugbọn Noa ri ojurere loju OLUWA.
9 Wọnyi ni ìtan Noa: Noa ṣe olõtọ ati ẹniti o pé li ọjọ́ aiye rẹ̀, Noa mba Ọlọrun rìn.
10 Noa si bí ọmọkunrin mẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti.