6 Inu OLUWA si bajẹ nitori ti o dá enia si aiye, o si dùn u de ọkàn rẹ̀.
7 OLUWA si wipe, Emi o pa enia ti mo ti dá run kuro li ori ilẹ; ati enia, ati ẹranko, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun; nitori inu mi bajẹ ti mo ti dá wọn.
8 Ṣugbọn Noa ri ojurere loju OLUWA.
9 Wọnyi ni ìtan Noa: Noa ṣe olõtọ ati ẹniti o pé li ọjọ́ aiye rẹ̀, Noa mba Ọlọrun rìn.
10 Noa si bí ọmọkunrin mẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti.
11 Aiye si bajẹ niwaju Ọlọrun, aiye si kún fun ìwa-agbara.
12 Ọlọrun si bojuwò aiye, si kiye si i, o bajẹ; nitori olukuluku enia ti bà ìwa rẹ̀ jẹ li aiye.