1 OLUWA si wi fun Noa pe, iwọ wá, ati gbogbo awọn ara ile rẹ sinu ọkọ̀, nitori iwọ ni mo ri li olododo niwaju mi ni iran yi.
2 Ninu onirũru ẹran ti o mọ́ meje meje ni ki iwọ ki o mu wọn, ati akọ ati abo rẹ̀; ati ninu ẹran ti kò mọ́ meji meji, ati akọ ati abo rẹ̀.
3 Ninu ẹiyẹ oju-ọrun pẹlu ni meje meje, ati akọ ati abo; lati dá irú si lãye lori ilẹ gbogbo.
4 Nitori ijọ́ meje si i, emi o mu òjo rọ̀ si ilẹ li ogoji ọsán ati li ogoji oru; ohun alãye gbogbo ti mo dá li emi o parun kuro lori ilẹ.
5 Noa si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun u.
6 Noa si jẹ ẹni ẹgbẹta ọdún nigbati kíkun-omi de si aiye.