23 Awọn iranṣẹ ọba Siria si wi fun u pe, ọlọrun wọn, ọlọrun oke ni; nitorina ni nwọn ṣe li agbara jù wa lọ; ṣugbọn jẹ ki a ba wọn jà ni pẹtẹlẹ, awa o si li agbara jù wọn lọ nitõtọ.
24 Nkan yi ni ki o si ṣe, mu awọn ọba kuro, olukuluku kuro ni ipò rẹ̀, ki o si fi olori-ogun si ipò wọn.
25 Ki o si kà iye ogun fun ara rẹ gẹgẹ bi ogun ti o ti fọ́, ẹṣin fun ẹṣin, ati kẹkẹ́ fun kẹkẹ́: awa o si ba wọn jà ni pẹ̀tẹlẹ, nitõtọ awa o li agbara jù wọn lọ. O si fi eti si ohùn wọn, o si ṣe bẹ̃.
26 O si ṣe li amọdun, ni Benhadadi kà iye awọn ara Siria, nwọn si goke lọ si Afeki, lati bá Israeli jagun.
27 A si ka iye awọn ọmọ Israeli, nwọn si pese onjẹ, nwọn si lọ ipade wọn: awọn ọmọ Israeli si dó niwaju wọn gẹgẹ bi agbo ọmọ ewurẹ kekere meji: ṣugbọn awọn ara Siria kún ilẹ na.
28 Enia Ọlọrun kan si wá, o si sọ fun ọba Israeli, o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nitoriti awọn ara Siria wipe, Oluwa, Ọlọrun oke ni, ṣugbọn on kì iṣe Ọlọrun afonifoji, nitorina emi o fi gbogbo ọ̀pọlọpọ enia yi le ọ lọwọ́, ẹnyin o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.
29 Nwọn si dó, ekini tì ekeji ni ijọ meje. O si ṣe, li ọjọ keje, nwọn padegun, awọn ọmọ Israeli si pa ọkẹ marun ẹlẹsẹ̀ ninu awọn ara Siria li ọjọ kan.