7 Ki ẹnyin ki o má si ṣe jade kuro lati ibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki ẹnyin ki o má ba kú: nitoripe oróro itasori OLUWA mbẹ lara nyin. Nwọn si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose.
8 OLUWA si sọ fun Aaroni pe,
9 Máṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, iwọ, tabi awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ, nigbati ẹnyin ba wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, ki ẹnyin ki o má ba kú: ìlana ni titilai ni iraniran nyin:
10 Ki ẹnyin ki o le ma fi ìyatọ sãrin mimọ́ ati aimọ́, ati sãrin ẽri ati ailẽri;
11 Ati ki ẹnyin ki o le ma kọ́ awọn ọmọ Israeli ni gbogbo ìlana ti OLUWA ti sọ fun wọn lati ọwọ́ Mose wá.
12 Mose si wi fun Aaroni, ati fun Eleasari ati fun Itamari, awọn ọmọ rẹ̀ ti o kù pe, Ẹ mú ẹbọ ohunjijẹ ti o kù ninu ẹbọ OLUWA, ti a fi iná ṣe, ki ẹ si jẹ ẹ lainí iwukàra lẹba pẹpẹ: nitoripe mimọ́ julọ ni:
13 Ki ẹnyin ki o si jẹ ẹ ni ibi mimọ́, nitoripe ipín tirẹ, ati ipín awọn ọmọ rẹ ni, ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: nitoripe, bẹ̃li a fi aṣẹ fun mi.