1 BI ẹnikan ba si ṣẹ̀, ti o si gbọ́ ohùn ibura, ti o si ṣe ẹlẹri, bi on ba ri tabi bi on ba mọ̀, ti kò ba wi, njẹ ki o rù aiṣedede rẹ̀.
2 Tabi bi ẹnikan ba farakàn ohun alaimọ́ kan, iba ṣe okú ẹranko alaimọ́, tabi okú ẹranọ̀sin alaimọ́, tabi okú ohun ti nrakò alaimọ́, ti o ba si pamọ́ fun u, on pẹlu yio si ṣe alaimọ́, yio si jẹbi:
3 Tabi bi o ba farakàn ohun aimọ́ ti enia, ohunkohun aimọ́ ti o wù ki o ṣe ti a fi sọ enia di elẽri, ti o ba si pamọ́ fun u; nigbati o ba mọ̀, nigbana ni on yio jẹbi:
4 Tabi bi ẹnikan ba bura, ti o nfi ète rẹ̀ sọ ati ṣe ibi, tabi ati ṣe rere, ohunkohun ti o wù ki o ṣe ti enia ba fi ibura sọ, ti o ba si pamọ́ fun u; nigbati o ba mọ̀, nigbana ni on yio jẹbi ọkan ninu ohun wọnyi:
5 Yio si ṣe, nigbati o ba jẹbi ọkan ninu ohun wọnyi, ki o jẹwọ pe on ti ṣẹ̀ li ohun na.
6 Ki o si mú ẹbọ ẹbi rẹ̀ wá fun OLUWA, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, abo lati inu agbo-ẹran wá, ọdọ-agutan tabi ọmọ ewurẹ kan, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
7 Bi kò ba si le mú ọdọ-agutan wá, njẹ ki o mú àdaba meji tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá fun ẹbọ ẹbi fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀; ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun.
8 Ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá, ẹniti yio tète rubọ eyiti iṣe ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti yio si mi i li ọrùn, ṣugbọn ki yio pín i meji:
9 Ki o si fi ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì wọ́n ìha pẹpẹ; ati ẹ̀jẹ iyokù ni ki a ro si isalẹ pẹpẹ na: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.
10 Ki o si ru ekeji li ẹbọ sisun, gẹgẹ bi ìlana na: ki alufa ki o si ṣètutu fun u, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i.
11 Ṣugbọn bi on kò ba le mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá, njẹ ki ẹniti o ṣẹ̀ na ki o mú idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun daradara wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki o máṣe fi oróro si i, bẹ̃ni ki o máṣe fi turari sori rẹ̀: nitoripe ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.
12 Nigbana ni ki o mú u tọ̀ alufa wá, ki alufa ki o si bù ikunwọ rẹ̀ kan ninu rẹ̀, ani ẹbọ-iranti rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ na, gẹgẹ bi ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.
13 Ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀ li ọkan ninu wọnyi, a o si dari rẹ̀ jì i: iyokù si jẹ́ ti alufa, bi ẹbọ ohunjijẹ.
14 OLUWA si sọ fun Mose pe,
15 Bi ẹnikan ba ṣìṣe, ti o ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀ ninu ohun mimọ́ OLUWA; nigbana ni ki o múwa fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran wá, ni idiyele rẹ nipa ṣekeli fadakà, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.
16 Ki o si ṣe atunṣe nitori ibi ti o ti ṣe ninu ohun mimọ́, ki o si fi idamarun pẹlu rẹ̀, ki o si fi i fun alufa: alufa yio si fi àgbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ na ṣètutu fun u, a o si dari rẹ̀ jì i.
17 Bi ẹnikan ba si ṣẹ̀, ti o ba si ṣe ọkan ninu nkan wọnyi, eyiti ofin OLUWA kọ̀ lati ṣe; bi kò tilẹ mọ̀, ṣugbọn o jẹbi, yio si rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
18 Ki o si mú àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran tọ̀ alufa wá ni idiyele rẹ, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori aimọ̀ rẹ̀ ninu eyiti o ṣìṣe ti kò si mọ̀, a o si dari rẹ̀ jì i.
19 Ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni: nitõtọ li o dẹ̀ṣẹ si OLUWA.