Lef 8 YCE

Ìyàsímímọ́ Aaroni ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀

1 OLUWA si sọ fun Mose pe,

2 Mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati ẹ̀wu wọnni, ati oróro itasori, ati akọmalu kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo meji, ati agbọ̀n àkara alaiwu kan;

3 Ki iwọ ki o si pè gbogbo ijọ enia jọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.

4 Mose si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun u; a si pe awọn enia jọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.

5 Mose si wi fun ijọ enia pe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ lati ṣe.

6 Mose si mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wá, o si fi omi wẹ̀ wọn.

7 O si wọ̀ ọ li ẹ̀wu, o si fi amure dì i, o si fi aṣọ igunwa wọ̀ ọ, o si wọ̀ ọ li ẹ̀wu-efodi, o si fi onirũru-ọ̀na ọjá ẹ̀wu-efodi dì i, o si fi gbà a li ọjá.

8 O si dì igbàiya mọ́ ọ; o si fi Urimu ati Tummimu sinu igbàiya na.

9 O si fi fila dé e li ori; ati lara fila na pẹlu, ani niwaju rẹ̀, li o fi awo wurà na si, adé mimọ́ nì; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

10 Mose si mú oróro itasori, o si ta a sara agọ́, ati sara ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, o si yà wọn simimọ́.

11 O si mú ninu rẹ̀ fi wọ́n ori pẹpẹ nigba meje, o si ta a sara pẹpẹ na, ati si gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀, lati yà wọn simimọ́.

12 O si dà ninu oróro itasori si ori Aaroni, o si ta a si i lara, lati yà a simimọ́.

13 Mose si mú awọn ọmọ Aaroni wá, o si fi ẹ̀wu wọ̀ wọn, o si fi amure di wọn, o si fi fila dé wọn li ori; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

14 O si mú akọmalu wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ fọwọ́ wọn lé ori akọmalu na fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.

15 O si pa a; Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si fi iká rẹ̀ tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ na yiká, o si wẹ̀ pẹpẹ na mọ́, o si dà ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ, o si yà a simimọ́, lati ṣètutu fun u.

16 O si mú gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, ati iwe mejeji, ati ọrá wọn, Mose si sun u lori pẹpẹ.

17 Ṣugbọn akọmalu na, ati awọ rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati igbẹ́ rẹ̀, on li o fi iná sun lẹhin ibudó; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

18 O si mú àgbo ẹbọ sisun wá: Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ si fọwọ́ wọn lé ori àgbo na.

19 O si pa a: Mose si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ yiká.

20 O si kun àgbo na; Mose si sun ori rẹ̀, ati ara rẹ̀, ati ọrá na.

21 O si ṣìn ifun rẹ̀ ati itan rẹ̀ ninu omi; Mose si sun gbogbo àgbo na lori pẹpẹ: ẹbọ sisun fun õrùn didùn ni: ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

22 O si mú àgbo keji wá, àgbo ìyasimimọ́: Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ si fọwọ́ wọn lé ori àgbo na.

23 O si pa a; Mose si mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, o si tọ́ ọ si eti ọtún Aaroni, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀.

24 O si mú awọn ọmọ Aaroni wá, Mose si tọ́ ninu ẹ̀jẹ na si eti ọtún wọn, ati si àtampako ọwọ́ ọtún wọn, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún wọn: Mose si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ yiká.

25 O si mú ọrá na, ati ìru ti o lọrá, ati gbogbo ọrá ti o mbẹ lara ifun, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, ati iwe mejeji, ati ọrá wọn, ati itan ọtún:

26 Ati lati inu agbọ̀n àkara alaiwu, ti o wà niwaju OLUWA, o mú adidùn àkara alaiwu kan, ati adidùn àkara oloróro kan, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan, o si fi wọn sori ọrá nì, ati si itan ọtún na:

27 O si fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni li ọwọ́, ati lé ọwọ́ awọn ọmọ rẹ̀, o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA.

28 Mose si gbà wọn li ọwọ́ wọn, o si sun wọn lori pẹpẹ li ẹbọ sisun: ìyasimimọ́ ni nwọn fun õrùn didùn: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.

29 Mose si mú igẹ̀ ẹran na, o si fì i li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: nitori ipín ti Mose ni ninu àgbo ìyasimimọ́; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

30 Mose si mú ninu oróro itasori nì, ati ninu ẹ̀jẹ ti mbẹ lori pẹpẹ, o si fi i wọ́n ara Aaroni, ati ara aṣọ rẹ̀ wọnni, ati ara awọn ọmọ rẹ̀, ati ara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; o si yà Aaroni simimọ́, ati aṣọ rẹ̀ wọnni, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀.

31 Mose si wi fun Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ bọ̀ ẹran na li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin si jẹ ẹ pẹlu àkara nì ti mbẹ ninu agbọ̀n ìyasimimọ́, bi mo ti fi aṣẹ lelẹ wipe, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ni ki o jẹ ẹ.

32 Eyiti o ba si kù ninu ẹran na ati ninu àkara na ni ki ẹnyin ki o fi iná sun.

33 Ki ẹnyin ki o máṣe jade si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ ni ijọ́ meje, titi ọjọ́ ìyasimimọ́ nyin yio fi pé; nitori ijọ́ meje ni a o fi yà nyin simimọ́.

34 Bi o ti ṣe li oni yi, bẹ̃li OLUWA fi aṣẹ lelẹ lati ṣe, lati ṣètutu fun nyin.

35 Nitorina ni ki ẹnyin ki o joko nibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, li ọsán ati li oru ni ijọ́ meje, ki ẹnyin ki o si ma pa aṣẹ OLUWA mọ́, ki ẹnyin ki o má ba kú: nitoripe bẹ̃li a fi aṣẹ fun mi.

36 Bẹ̃li Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun gbogbo ti OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ lati ọwọ́ Mose wá.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27