Lef 7 YCE

Ẹbọ Ìmúkúrò Ẹ̀bi

1 EYI si li ofin ẹbọ ẹbi: mimọ́ julọ ni.

2 Ni ibi ti nwọn gbé pa ẹbọ sisun ni ki nwọn ki o pa ẹbọ ẹbi: ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ yiká.

3 Ki o si fi gbogbo ọrá inu rẹ̀ rubọ; ìru rẹ̀ ti o lọrá, ati ọrá ti o bò ifun lori,

4 Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe, on ni ki o mú kuro:

5 Ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ẹbọ ẹbi ni.

6 Gbogbo ọkunrin ninu awọn alufa ni ki o jẹ ninu rẹ̀: ni ibi mimọ́ kan ki a jẹ ẹ: mimọ́ julọ ni.

7 Bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ si li ẹbọ ẹbi: ofin kan ni fun wọn: alufa ti nfi i ṣètutu ni ki on ní i.

8 Ati alufa ti nru ẹbọ sisun ẹnikẹni, ani alufa na ni yio ní awọ ẹran ẹbọ sisun, ti o ru fun ara rẹ̀.

9 Ati gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti a yan ninu àro, ati gbogbo eyiti a yan ninu apẹ, ati ninu awopẹtẹ, ni ki o jẹ́ ti alufa ti o ru u.

10 Ati gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti a fi oróro pò, ati gbigbẹ, ni ki gbogbo awọn ọmọ Aaroni ki o ní, ẹnikan bi ẹnikeji rẹ̀.

Ẹbọ Alaafia

11 Eyi si ni ofin ẹbọ alafia, ti on o ru si OLUWA.

12 Bi o ba mú u wá fun idupẹ́, njẹ ki o mú adidùn àkara alaiwu wá ti a fi oróro pò, pẹlu ẹbọ ọpẹ́ rẹ̀, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si, ati adidùn àkara iyẹfun didara, ti a fi oróro pò, ti a din.

13 Pẹlu adidùn àkara wiwu ki o mú ọrẹ-ẹbọ pẹlu ẹbọ alafia rẹ̀ wa fun idupẹ́.

14 Ati ninu rẹ̀ ni ki o mú ọkan kuro ninu gbogbo ọrẹ-ẹbọ na fun ẹbọ agbesọsoke si OLUWA; ki o si jẹ́ ti alufa ti o nwọ́n ẹ̀jẹ ẹbọ alafia.

15 Ati ẹran ẹbọ alafia rẹ̀ fun idupẹ́, ki a jẹ ẹ li ọjọ́ na ti a fi rubọ; ki o máṣe kù ninu rẹ̀ silẹ titi di owurọ̀.

16 Ṣugbọn bi ẹbọ-ọrẹ rẹ̀ ba ṣe ti ẹjẹ́, tabi ọrẹ-ẹbọ atinuwá, ki a jẹ ẹ li ọjọ́ na ti o ru ẹbọ rẹ̀: ati ni ijọ́ keji ni ki a jẹ iyokù rẹ̀ pẹlu:

17 Ṣugbọn iyokù ninu ẹran ẹbọ na ni ijọ́ kẹta ni ki a fi iná sun.

18 Bi a ba si jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia rẹ̀ rára ni ijọ́ kẹta, ki yio dà, bẹ̃li a ki yio kà a si fun ẹniti o ru u: irira ni yio jasi, ọkàn ti o ba si jẹ ẹ yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

19 Ẹran ti o ba si kàn ohun aimọ́ kan, a kò gbọdọ jẹ ẹ; sisun ni ki a fi iná sun u. Ṣugbọn ẹran na ni, gbogbo ẹniti o mọ́ ni ki o jẹ ninu rẹ̀.

20 Ṣugbọn ọkàn na ti o ba jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia, ti iṣe ti OLUWA, ti on ti ohun aimọ́ rẹ̀ lara rẹ̀, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.

21 Pẹlupẹlu ọkàn na ti o ba fọwọkàn ohun aimọ́ kan, bi aimọ́ enia, tabi ẹranko alaimọ́, tabi ohun irira elẽri, ti o si jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia, ti iṣe ti OLUWA, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.

22 OLUWA si sọ fun Mose pe,

23 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ọrákọra akọmalu, tabi ti agutan, tabi ti ewurẹ.

24 Ati ọrá ẹran ti o tikara rẹ̀ kú, ati ọrá eyiti ẹranko fàya, on ni ki a ma lò ni ilò miran: ṣugbọn ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ.

25 Nitoripe ẹnikẹni ti o ba jẹ ọrá ẹran, ninu eyiti enia mú rubọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ani ọkàn ti o ba jẹ ẹ on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.

26 Pẹlupẹlu ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ, iba ṣe ti ẹiyẹ tabi ti ẹran, ninu ibugbé nyin gbogbo.

27 Ọkànkọkàn ti o ba jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.

28 OLUWA si sọ fun Mose pe,

29 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹniti o ba ru ẹbọ alafia rẹ̀ si OLUWA, ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ tọ̀ OLUWA wá ninu ẹbọ alafia rẹ̀:

30 Ọwọ́ on tikara rẹ̀ ni ki o fi mú ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe wá; ọrá pẹlu igẹ̀ rẹ̀, on ni ki o múwa, ki a le fì igẹ̀ na li ẹbọ fifì niwaju OLUWA.

31 Ki alufa na ki o sun ọrá na lori pẹpẹ: ṣugbọn ki igẹ̀ na ki o jẹ́ ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀.

32 Itan ọtún ni ki ẹnyin ki o fi fun alufa, fun ẹbọ agbesọsoke ninu ẹbọ alafia nyin.

33 Ninu awọn ọmọ Aaroni ẹniti o rubọ ẹ̀jẹ ẹbọ alafia, ati ọrá, ni ki o ní itan ọtun fun ipín tirẹ̀.

34 Nitoripe igẹ̀ fifì ati itan agbeṣọsoke, ni mo gbà lọwọ awọn ọmọ Israeli ninu ẹbọ alafia wọn, mo si fi wọn fun Aaroni alufa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ nipa ìlana titilai, lati inu awọn ọmọ Israeli.

35 Eyi ni ipín Aaroni, ati ìpín awọn ọmọ rẹ̀, ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, li ọjọ́ na ti o mú wọn wá lati ṣe alufa OLUWA;

36 Ti OLUWA palaṣẹ lati fi fun wọn lati inu awọn ọmọ Israeli, li ọjọ́ ti o fi oróro yàn wọn. Ìlana lailai ni iraniran wọn.

37 Eyi li ofin ẹbọ sisun, ti ẹbọ ohunjijẹ, ati ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ti ẹbọ ẹbi, ati ti ìyasimimọ́, ati ti ẹbọ alafia;

38 Ti OLUWA palaṣẹ fun Mose li òke Sinai, li ọjọ́ ti o paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli lati ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá fun OLUWA ni ijù Sinai.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27