Lef 11 YCE

Àwọn Ẹranko Tí Ó Tọ̀nà láti Jẹ

1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni, o wi fun wọn pe,

2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Wọnyi li ẹranko ti ẹnyin o ma jẹ ninu gbogbo ẹran ti mbẹ lori ilẹ aiye.

3 Ohunkohun ti o ba yà bàta-ẹsẹ̀, ti o si là li ẹsẹ̀, ti o si njẹ apọjẹ, ninu ẹran, on ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.

4 Ṣugbọn wọnyi ni ki ẹ máṣe jẹ ninu awọn ti njẹ apọjẹ, tabi awọn ti o si yà bàta-ẹsẹ̀: bi ibakasiẹ, nitoriti o njẹ apọjẹ ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ, alaimọ́ li o jasi fun nyin.

5 Ati gara, nitoriti o njẹ apọjẹ, ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ li o jasi fun nyin.

6 Ati ehoro, nitoriti o njẹ apọjẹ, ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ li o jasi fun nyin.

7 Ati ẹlẹdẹ̀, bi o ti yà bàta-ẹsẹ̀, ti o si là ẹsẹ̀, ṣugbọn on kò jẹ apọjẹ, alaimọ́ li o jasi fun nyin.

8 Ninu ẹran wọn li ẹnyin kò gbọdọ jẹ, okú wọn li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn; alaimọ́ ni nwọn jasi fun nyin.

9 Wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo ohun ti mbẹ ninu omi: ohunkohun ti o ba ní lẹbẹ ati ipẹ́, ninu omi, ninu okun, ati ninu odò, awọn ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.

10 Ati gbogbo eyiti kò ní lẹbẹ ati ipẹ́ li okun, ati li odò, ninu gbogbo ohun ti nrá ninu omi, ati ninu ohun alãye kan ti mbẹ ninu omi, irira ni nwọn o jasi fun nyin,

11 Ani irira ni nwọn o ma jẹ́ fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu ẹran wọn, okú wọn ni ẹ o sì kàsi irira.

12 Ohunkohun ti kò ba ní lẹbẹ ati ipẹ́, ninu omi, on ni ki ẹnyin kàsi irira fun.

13 Wọnyi li ẹnyin o si ma kàsi irira ninu ẹiyẹ; awọn li a kò gbọdọ jẹ, irira ni nwọn iṣe: idì, ati aṣá-idì, ati idì-ẹja.

14 Ati igún, ati aṣá li onirũru rẹ̀;

15 Ati gbogbo ìwo li onirũru rẹ̀;

16 Ati ogongo, ati owiwi, ati ẹlulu, ati awodi li onirũru rẹ̀,

17 Ati òyo ati ìgo, ati owiwi;

18 Ati ogbugbu, ati ofù, ati àkala;

19 Ati àkọ, ati ondẹ li onirũru rẹ̀, ati atọka, ati adán.

20 Gbogbo ohun ti nrakò, ti nfò ti o si nfi mẹrẹrin rìn ni ki ẹnyin kàsi irira fun nyin.

21 Ṣugbọn wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo ohun ti nfò, ti nrakò, ti nfi gbogbo mẹrẹrin rìn, ti o ní tete lori ẹsẹ̀ wọn, lati ma fi ta lori ilẹ;

22 Ani ninu wọnyi ni ki ẹnyin ma jẹ; eṣú ni irú rẹ̀, ati eṣú onihoho nipa irú rẹ̀, ati ọbọnbọn nipa irú rẹ̀, ati ẹlẹnga nipa irú rẹ̀.

23 Ṣugbọn gbogbo ohun iyokù ti nfò ti nrakò, ti o ní ẹsẹ̀ mẹrin, on ni ki ẹnyin kàsi irira fun nyin.

24 Nitori wọnyi li ẹnyin o si jẹ́ alaimọ́: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ:

25 Ẹnikẹni ti o ba si rù ohun kan ninu okú wọn ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

26 Ẹranko gbogbo ti o yà bàta-ẹsẹ̀, ti kò si là ẹsẹ̀, tabi ti kò si jẹ apọjẹ, ki o jẹ́ alaimọ́ fun nyin: gbogbo ẹniti o ba farakàn wọn ki o jẹ́ alaimọ́.

27 Ati ohunkohun ti o ba si nrìn lori ẽkanna rẹ̀, ninu gbogbo onirũru ẹranko, ti nfi ẹsẹ̀ mẹrẹrin rìn, alaimọ́ ni nwọn fun nyin: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

28 Ẹniti o ba si rù okú wọn ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: alaimọ́ ni nwọn fun nyin.

29 Wọnyi ni yio si jasi alaimọ́ fun nyin ninu ohun ti nrakò lori ilẹ; ase, ati eku, ati awun nipa irú rẹ̀.

30 Ati ọmọ̃le, ati ahanhan, ati alãmu, ati agiliti, ati agẹmọ.

31 Wọnyi li alaimọ́ fun nyin ninu gbogbo ohun ti nrakò: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

32 Ati lara ohunkohun ti okú wọn ba ṣubulù, ki o jasi alaimọ́; ibaṣe ohun èlo-igi, tabi aṣọ, tabi awọ, tabi àpo, ohunèlo ti o wù ki o ṣe, ninu eyiti a nṣe iṣẹ kan, a kò gbọdọ má fi bọ̀ inu omi, on o si jasi alaimọ́ titi di aṣalẹ; bẹ̃li a o si sọ ọ di mimọ́.

33 Ati gbogbo ohunèlo amọ̀, ninu eyiti ọkan ninu okú nwọn ba bọ́ si, ohunkohun ti o wù ki o wà ninu rẹ̀ yio di alaimọ́, ki ẹnyin ki o si fọ́ ọ.

34 Ninu onjẹ gbogbo ti a o ba jẹ, ti irú omi nì ba dà si, yio di alaimọ́: ati ohun mimu gbogbo ti a o ba mu ninu irú ohunèlo na yio di alaimọ́.

35 Ati ohunkohun lara eyiti ninu okú wọn ba ṣubulù, yio di alaimọ́; iba ṣe àro, tabí idana, wiwó ni ki a wó wọn lulẹ: alaimọ́ ni nwọn, nwọn o si jẹ́ alaimọ́ fun nyin.

36 Ṣugbọn orisun tabi kanga kan, ninu eyiti omi pupọ̀ gbé wà, yio jẹ́ mimọ́: ṣugbọn eyiti o ba kàn okú wọn yio jẹ́ alaimọ́.

37 Bi ninu okú wọn ba bọ́ sara irugbìn kan ti iṣe gbigbìn, yio jẹ́ mimọ́.

38 Ṣugbọn bi a ba dà omi sara irugbìn na, ti ninu okú wọn ba si bọ́ sinu rẹ̀, yio si jẹ́ alaimọ́ fun nyin.

39 Ati bi ẹran kan, ninu eyiti ẹnyin ba ma jẹ, ba kú; ẹniti o ba farakàn okú rẹ̀ yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

40 Ẹniti o ba si jẹ ninu okú rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ẹniti o ba si rù okú rẹ̀ ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

41 Ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ yio jasi irira; a ki yio jẹ ẹ.

42 Ohunkohun ti nfi inu wọ́, ati ohunkohun ti nfi mẹrẹrin rìn, ati ohunkohun ti o ba ní ẹsẹ̀ pupọ̀, ani ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ, awọn li ẹnyin kò gbọdọ jẹ; nitoripe irira ni nwọn.

43 Ẹnyin kò gbọdọ fi ohun kan ti nrakò, sọ ara nyin di irira, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fi wọn sọ ara nyin di alaimọ́ ti ẹnyin o fi ti ipa wọn di elẽri.

44 Nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin: nitorina ni ki ẹnyin ki o yà ara nyin si mimọ́, ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́; nitoripe mimọ́ li Emi: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fi ohunkohun ti nrakò sọ ara nyin di elẽri.

45 Nitoripe Emi li OLUWA ti o mú nyin gòke ti ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: nitorina ki ẹnyin ki o jẹ́ mimọ́, nitoripe mimọ́ li Emi.

46 Eyiyi li ofin ẹranko, ati ti ẹiyẹ, ati ti ẹda gbogbo alãye ti nrá ninu omi, ati ti ẹda gbogbo ti nrakò lori ilẹ:

47 Lati fi iyatọ sãrin aimọ́ ati mimọ́, ati sãrin ohun alãye ti a ba ma jẹ, ati ohun alãye ti a ki ba jẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27