Lef 17 YCE

Ẹ̀jẹ̀ Lọ́wọ̀–Ninu Rẹ̀ Ni Ẹ̀mí wà

1 OLUWA si sọ fun Mose pe,

2 Sọ fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe; Eyi li ohun ti OLUWA ti palaṣẹ, wipe,

3 Ẹnikẹni ti iṣe enia ile Israeli, ti o ba pa akọmalu tabi ọdọ-agutan, tabi ewurẹ, ninu ibudó, tabi ti o pa a lẹhin ibudó,

4 Ti kò si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, lati ru u li ẹbọ wi OLUWA niwaju agọ́ OLUWA: a o kà ẹ̀jẹ si ọkunrin na lọrùn, o ta ẹ̀jẹ silẹ; ọkunrin na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀:

5 Nitori idí eyi pe, ki awọn ọmọ Israeli ki o le ma mú ẹbọ wọn wá, ti nwọn ru ni oko gbangba, ani ki nwọn ki o le mú u tọ̀ OLUWA wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, sọdọ alufa, ki o si ru wọn li ẹbọ alafia si OLUWA.

6 Ki alufa ki o si bù ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki o si sun ọrá na fun õrùn didún si OLUWA.

7 Ki nwọn ki o má si ṣe ru ẹbọ wọn si obukọ mọ́, ti nwọn ti ntọ̀ lẹhin ṣe àgbere. Eyi ni yio ma ṣe ìlana lailai fun wọn ni iran-iran wọn.

8 Ki iwọ ki o si wi fun wọn, Ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti o ru ẹbọ sisun tabi ẹbọ kan,

9 Ti kò si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, lati ru u si OLUWA; ani ọkunrin na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.

10 Ati ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti o ba jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ; ani emi o kọ oju mi si ọkàn na ti o jẹ ẹ̀jẹ, emi o si ke e kuro ninu awọn enia rẹ̀.

11 Nitoripe ẹmi ara mbẹ ninu ẹ̀jẹ: emi si ti fi i fun nyin lati ma fi ṣètutu fun ọkàn nyin lori pẹpẹ nì: nitoripe ẹ̀jẹ ni iṣe ètutu fun ọkàn.

12 Nitorina ni mo ṣe wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọkàn kan ninu nyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ, bẹ̃li alejò kan ti nṣe atipo ninu nyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ.

13 Ati ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Israeli, tabi ninu awọn alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti nṣe ọdẹ ti o si mú ẹranko tabi ẹiyẹ ti a ba jẹ; ani ki o ro ẹ̀jẹ rẹ̀ dànu, ki o si fi erupẹ bò o.

14 Nitoripe ẹmi gbogbo ara ni, ẹ̀jẹ rẹ̀ ni ẹmi rẹ̀: nitorina ni mo ṣe wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ ẹrankẹran: nitoripe ẹ̀jẹ li ẹmi ara gbogbo: ẹnikẹni ti o ba jẹ ẹ li a o ke kuro.

15 Ati gbogbo ọkàn ti o ba jẹ ẹran ti o tikara rẹ̀ kú, tabi eyiti a fàya, iba ṣe ọkan ninu awọn ibilẹ, tabi alejò, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: nigbana li on o mọ́.

16 Ṣugbọn bi kò ba fọ̀ wọn, tabi ti kò si wẹ̀ ara rẹ̀; njẹ on o rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27