Lef 21 YCE

Àwọn Àlùfáàa Gbọdọ̀ Jẹ́ Mímọ́

1 OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, ki o si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu awọn enia rẹ̀ kò gbọdọ di alaimọ́ nitori okú.

2 Bikoṣe fun ibatan rẹ̀ ti o sunmọ ọ, eyinì ni, iya rẹ̀, ati baba rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ rẹ̀ obinrin, ati arakunrin rẹ̀;

3 Ati arabinrin rẹ̀ ti iṣe wundia, ti o wà lọdọ rẹ̀, ti kò ti ilí ọkọ, nitori rẹ̀ ni ki o di alaimọ́.

4 Ṣugbọn on kò gbọdọ ṣe ara rẹ̀ li aimọ́, lati bà ara rẹ̀ jẹ́, olori kan sa ni ninu awọn enia rẹ̀.

5 Nwọn kò gbọdọ dá ori wọn fá, bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ tọ́ irungbọn wọn, tabi singbẹrẹ kan si ara wọn.

6 Ki nwọn ki o si jasi mimọ́ fun Ọlọrun wọn, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ Ọlọrun wọn jẹ́: nitoripe ẹbọ OLUWA ti a fi ina ṣe, ati àkara Ọlọrun wọn, ni nwọn fi nrubọ: nitorina ni ki nwọn ki o jẹ́ mimọ́.

7 Nwọn kò gbọdọ fẹ́ aya ti iṣe àgbere, tabi ẹni ibàjẹ́; bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fẹ́ obinrin ti a ti ọdọ ọkọ rẹ̀ kọ̀silẹ: nitoripe mimọ́ li on fun Ọlọrun rẹ̀.

8 Nitorina ki ẹnyin ki o yà a simimọ́; nitoriti o nrubọ àkara Ọlọrun rẹ: yio jẹ́ mimọ́ si ọ: nitoripe mimọ́ li Emi OLUWA, ti o yà nyin simimọ́.

9 Ati bi ọmọbinrin alufa kan, ba fi iṣẹ àgbere bà ara rẹ̀ jẹ́, o bà baba rẹ̀ jẹ́: iná li a o da sun u.

10 Ati olori alufa ninu awọn arakunrin rẹ̀, ori ẹniti a dà oróro itasori si, ti a si yàsọtọ lati ma wọ̀ aṣọ wọnni, ki o máṣe ṣi ibori rẹ̀, tabi ki o fà aṣọ rẹ̀ ya;

11 Ki o má si ṣe wọle tọ̀ okú kan lọ, bẹ̃ni ki o máṣe sọ ara rẹ̀ di alaimọ́ nitori baba rẹ̀, tabi nitori iya rẹ̀;

12 Bẹ̃ni ki o máṣe jade kuro ninu ibi mimọ́, bẹ̃ni ki o máṣe bà ibi mimọ́ Ọlọrun rẹ̀ jẹ́, nitoripe adé oróro itasori Ọlọrun rẹ̀ mbẹ lori rẹ̀: Emi li OLUWA.

13 Wundia ni ki o fẹ́ li aya fun ara rẹ̀.

14 Opó, tabi obinrin ikọsilẹ, tabi ẹni-ibàjẹ́, tabi panṣaga, wọnyi ni on kò gbọdọ fẹ́: bikoṣe wundia ni ki o fẹ́ li aya lati inu awọn enia rẹ̀.

15 Bẹ̃ni ki o máṣe bà irú-ọmọ rẹ̀ jẹ́ ninu awọn enia rẹ̀: nitoripe Emi li OLUWA ti o yà a simimọ́.

16 OLUWA si sọ fun Mose pe,

17 Sọ fun Aaroni pe, Ẹnikẹni ninu irú-ọmọ rẹ ni iran-iran wọn, ti o ní àbuku kan, ki o máṣe sunmọtosi lati rubọ àkara Ọlọrun rẹ̀.

18 Nitoripe gbogbo ọkunrin ti o ní àbuku, ki o máṣe sunmọtosi: ọkunrin afọju, tabi amukun, tabi arẹ́mu, tabi ohun kan ti o leke,

19 Tabi ọkunrin ti iṣe aṣẹ́sẹ̀, tabi aṣẹ́wọ,

20 Tabi abuké, tabi arará, tabi ẹniti o ní àbuku kan li oju rẹ̀, tabi ti o ní ekuru, tabi ipẹ́, tabi ti kóro rẹ̀ fọ́;

21 Ẹnikẹni ti o ní àbuku ninu irúọmọ Aaroni alufa kò gbọdọ sunmọtosi lati ru ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: on li àbuku; kò gbọdọ sunmọtosi lati rubọ àkara Ọlọrun rẹ̀.

22 On o ma jẹ àkara Ọlọrun rẹ̀, ti mimọ́ julọ ati ti mimọ́.

23 Kìki on ki yio wọ̀ inu aṣọ-ikele nì lọ, bẹ̃ni ki o máṣe sunmọ pẹpẹ, nitoriti on ní àbuku; ki on ki o máṣe bà ibi mimọ́ mi jẹ́: nitori Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́.

24 Mose si wi fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ọmọ Israeli.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27