1 OLUWA si sọ fun Mose pe,
2 Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Israeli, tabi ninu awọn alejò ti nṣe atipo ni Israeli, ti o ba fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki; pipa ni ki a pa a: ki awọn enia ilẹ na ki o sọ ọ li okuta pa.
3 Emi o si kọju mi si ọkunrin na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀; nitoriti o fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki, lati sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́, ati lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ́.
4 Bi awọn enia ilẹ na ba si mú oju wọn kuro lara ọkunrin na, nigbati o ba fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki, ti nwọn kò si pa a:
5 Nigbana li emi o kọju si ọkunrin na, ati si idile rẹ̀, emi o si ke e kuro, ati gbogbo awọn ti o ṣe àgbere tọ̀ ọ lẹhin, lati ma ṣe àgbere tọ̀ Moleki lẹhin, lãrin awọn enia wọn.
6 Ati ọkàn ti o ba yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, ati ajẹ́, lati ṣe àgbere tọ̀ wọn lẹhin, ani emi o kọju mi si ọkàn na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀.
7 Nitorina ẹnyin yà ara nyin simimọ́, ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
8 Ki ẹnyin ki o si ma pa ìlana mi mọ́, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA ti nyà nyin simimọ́.
9 Ẹnikẹni ti o ba fi baba tabi iya rẹ̀ ré, pipa li a o pa a: o fi baba on iya rẹ̀ ré; ẹ̀jẹ rẹ̀ wà lori rẹ̀.
10 Ati ọkunrin na ti o bá aya ọkunrin miran ṣe panṣaga, ani on ti o bá aya ẹnikeji rẹ̀ ṣe panṣaga, panṣaga ọkunrin ati panṣaga obinrin li a o pa nitõtọ.
11 Ati ọkunrin ti o bá aya baba rẹ̀ dàpọ, o tú ìhoho baba rẹ̀: pipa li a o pa awọn mejeji; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.
12 Ọkunrin kan ti o ba bá aya ọmọ rẹ̀ dàpọ, pipa ni ki a pa awọn mejeji: nwọn ṣe rudurudu; ẹ̀jẹ wọn wà lori wọn.
13 Ati ọkunrin ti o ba bá ọkunrin dàpọ, bi ẹni ba obinrin dàpọ, awọn mejeji li o ṣe ohun irira: pipa li a o pa wọn; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.
14 Ati ọkunrin ti o ba fẹ́ obinrin ati iya rẹ̀, ìwabuburu ni: iná li a o fi sun wọn, ati on ati awọn; ki ìwabuburu ki o má ṣe sí lãrin nyin.
15 Ati ọkunrin ti o ba bá ẹranko dàpọ, pipa ni ki a pa a: ki ẹnyin ki o si pa ẹranko na.
16 Bi obinrin kan ba si sunmọ ẹranko kan, lati dubulẹ tì i, ki iwọ ki o pa obinrin na, ati ẹranko na: pipa ni ki a pa wọn; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.
17 Ati bi ọkunrin kan ba fẹ́ arabinrin rẹ̀, ọmọbinrin baba rẹ̀, tabi ọmọbinrin iya rẹ̀, ti o si ri ìhoho rẹ̀, ti on si ri ìhoho rẹ̀; ohun buburu ni; a o si ke wọn kuro loju awọn enia wọn: o tú ìhoho arabinrin rẹ̀; on o rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
18 Ati bi ọkunrin kan ba bá obinrin dàpọ ti o ní ohun obinrin rẹ̀ lara, ti o ba si tú u ni ìhoho; o tú isun rẹ̀ ni ìhoho, obinrin na si fi isun ẹ̀jẹ rẹ̀ hàn: awọn mejeji li a o si ke kuro lãrin awọn enia wọn.
19 Iwọ kò si gbọdọ tú ìhoho arabinrin iya rẹ, tabi ti arabinrin baba rẹ: nitoripe o tú ìhoho ibatan rẹ̀: nwọn o rù ẹ̀ṣẹ wọn.
20 Bi ọkunrin kan ba si bá aya arakunrin õbi rẹ̀ dàpọ, o tú ìhoho arakunrin õbi rẹ̀: nwọn o rù ẹ̀ṣẹ wọn; nwọn o kú li ailọmọ.
21 Bi ọkunrin kan ba si fẹ́ aya arakunrin rẹ̀, ohun-aimọ́ ni: o tú ìhoho arakunrin rẹ̀; nwọn o jẹ́ alailọmọ.
22 Nitorina li ẹnyin o ṣe ma pa gbogbo ìlana mi mọ́, ati gbogbo idajọ mi, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: ki ilẹ na, ninu eyiti mo mú nyin wá tẹ̀dó si, ki o má ṣe bì nyin jade.
23 Ẹnyin kò si gbọdọ rìn ninu ìlana orilẹ-ède, ti emi lé jade kuro niwaju nyin: nitoriti nwọn ṣe gbogbo wọnyi, nitorina ni mo ṣe korira wọn.
24 Ṣugbọn emi ti wi fun nyin pe, Ẹnyin o ní ilẹ wọn, ati pe emi o fi i fun nyin lati ní i, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o yà nyin sọ̀tọ kuro ninu awọn orilẹ-ède.
25 Nitorina ki ẹnyin ki o fi ìyatọ sãrin ẹranko mimọ́ ati alaimọ́, ati sãrin ẹiyẹ alaimọ́ ati mimọ́: ki ẹnyin ki o má si ṣe fi ẹranko, tabi ẹiyẹ, tabi ohunkohun alãye kan ti nrakò lori ilẹ, ti mo ti yàsọ̀tọ fun nyin bi alaimọ́, sọ ọkàn nyin di irira.
26 Ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́ fun mi: nitoripe mimọ́ li Emi OLUWA, mo si ti yà nyin sọ̀tọ kuro ninu awọn orilẹ-ède, ki ẹnyin ki o le jẹ́ ti emi.
27 Ọkunrin pẹlu tabi obinrin ti o ní ìmo afọṣẹ, tabi ti iṣe ajẹ́, pipa ni ki a pa a: okuta ni ki a fi sọ wọn pa: ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.