1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnikan ba ní àrun isun lara rẹ̀, nitori isun rẹ̀ alaimọ́ li on.
3 Eyi ni yio si jẹ́ aimọ́ rẹ̀ ninu isun rẹ̀: ara rẹ̀ iba ma sun isun rẹ̀, tabi bi ara rẹ̀ si dá kuro ninu isun rẹ̀, aimọ́ rẹ̀ ni iṣe.
4 Gbogbo ori akete ti ẹniti o ní isun na ba dubulẹ lé, aimọ́ ni: ati gbogbo ohun ti o joko lé yio jẹ́ alaimọ́.
5 Ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀ ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
6 Ẹniti o si joko lé ohunkohun ti ẹniti o ní isun ti joko lé, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
7 Ẹniti o si farakàn ara ẹniti o ní isun, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
8 Bi ẹniti o ní isun ba tutọ sara ẹniti o mọ́; nigbana ni ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
9 Ati asákasá ti o wù ki ẹniti o ní isun ki o gùn ki o jẹ́ alaimọ́.
10 Ẹnikẹni ti o ba farakàn ohun kan ti o wà nisalẹ rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ati ẹniti o rù ohun kan ninu nkan wọnni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
11 Ati ẹnikẹni ti ẹniti o ní isun ba farakàn, ti kò ti wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ ninu omi, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
12 Ati ohunèlo amọ̀, ti ẹniti o ní isun ba fọwọkàn, fifọ́ ni ki a fọ́ ọ: ati gbogbo ohunèlo igi ni ki a ṣàn ninu omi.
13 Nigbati ẹniti o ní isun ba si di mimọ́ kuro ninu isun rẹ̀, nigbana ni ki o kà ijọ́ meje fun ara rẹ̀, fun isọdimimọ́ rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi ti nṣàn, yio si jẹ́ mimọ́.
14 Ati ni ijọ́ kẹjọ, ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji fun ara rẹ̀, ki o si wá siwaju OLUWA si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki o si fi wọn fun alufa:
15 Ki alufa ki o si fi wọn rubọ, ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun; ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori isun rẹ̀.
16 Ati bi ohun irú ìdapọ ọkunrin ba ti ara rẹ̀ jade, nigbana ni ki o wẹ̀ gbogbo ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
17 Ati gbogbo aṣọ, ati gbogbo awọ, lara eyiti ohun irú ìdapọ ba wà, on ni ki a fi omi fọ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
18 Ati obinrin na, ẹniti ọkunrin ba bá dàpọ ti on ti ohun irú ìdapọ, ki awọn mejeji ki o wẹ̀ ninu omi, ki nwọn ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
19 Bi obinrin kan ba si ní isun, ti isun rẹ̀ li ara rẹ̀ ba jasi ẹ̀jẹ, ki a yà a sapakan ni ijọ́ meje: ẹnikẹni ti o ba si farakàn a, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
20 Ati ohun gbogbo ti o dubulẹ lé ninu ile ìyasapakan rẹ̀ yio jẹ́ aimọ́: ohunkohun pẹlu ti o joko lé yio jẹ́ aimọ́.
21 Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
22 Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn ohun kan ti o joko lé, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
23 Bi o ba si ṣepe lara akete rẹ̀ ni, tabi lara ohun ti o joko lé, nigbati o ba farakàn a, ki on ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
24 Bi ọkunrin kan ba si bá a dàpọ rára, ti ohun obinrin rẹ̀ ba mbẹ lara ọkunrin na, ki on ki o jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje; ati gbogbo akete ti on dubulẹ lé ki o jẹ́ aimọ́.
25 Ati bi obinrin kan ba ní isun ẹ̀jẹ li ọjọ́ pupọ̀ le ìgba ìyasapakan rẹ̀; tabi bi o ba si sun rekọja ìgba ìyasapakan rẹ̀; gbogbo ọjọ́ isun aimọ́ rẹ̀ yio si ri bi ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀: o jẹ́ alaimọ́.
26 Gbogbo akete ti o dubulẹ lé ni gbogbo ọjọ́ isun rẹ̀ ki o si jẹ́ fun u bi akete ìyasapakan rẹ̀: ati ohunkohun ti o joko lé ki o jẹ́ aimọ́, bi aimọ́ ìyasapakan rẹ̀.
27 Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn nkan wọnni ki o jẹ́ alaimọ́, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ̀ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
28 Ṣugbọn bi obinrin na ba di mimọ́ kuro ninu isun rẹ̀, nigbana ni ki o kà ijọ́ meje fun ara rẹ̀, lẹhin eyinì ni ki o si jẹ́ mimọ́.
29 Ati ni ijọ́ kẹjọ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji fun ara rẹ̀, ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
30 Ki alufa ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun; ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori isun aimọ́ rẹ̀.
31 Bayi ni ki ẹnyin ki o yà awọn ọmọ Israeli kuro ninu aimọ́ wọn; ki nwọn ki o má ba kú ninu aimọ́ wọn, nigbati nwọn ba sọ ibugbé mi ti mbẹ lãrin wọn di aimọ́.
32 Eyi li ofin ẹniti o ní isun, ati ti ẹniti ohun irú rẹ̀ jade lara rẹ̀, ti o si ti ipa rẹ̀ di alaimọ́;
33 Ati ti ẹniti o ri ohun obinrin rẹ̀, ati ti ẹniti o ní isun, ati ti ọkunrin, ati ti obinrin, ati ti ẹniti o ba bá ẹniti iṣe alaimọ́ dàpọ.