Lef 14 YCE

Ìwẹ̀nùmọ́ lẹ́yìn Àrùn Ara

1 OLUWA si sọ fun Mose pe,

2 Eyi ni yio ma ṣe ofin adẹ́tẹ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀: ki a mú u tọ̀ alufa wá:

3 Ki alufa ki o si jade sẹhin ibudó; ki alufa ki o si wò o, si kiyesi i, bi àrun ẹ̀tẹ na ba jiná li ara adẹ́tẹ na:

4 Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ pe, ki a mú ãye ẹiyẹ meji mimọ́ wá, fun ẹniti a o wẹ̀numọ́, pẹlu igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu:

5 Ki alufa ki o paṣẹ pe ki a pa ọkan ninu ẹiyẹ nì ninu ohunèlo àmọ li oju omi ti nṣàn:

6 Niti ẹiyẹ alãye, ki o mú u, ati igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu, ki o si fi wọn ati ẹiyẹ alãye nì bọ̀ inu ẹ̀jẹ ẹiyẹ ti a pa li oju omi ti nṣàn:

7 Ki o si fi wọ́n ẹniti a o wẹ̀numọ́ kuro ninu ẹ̀tẹ nigba meje, ki o si pè e ni mimọ́, ki o si jọwọ ẹiyẹ alãye nì lọwọ lọ si gbangba oko.

8 Ki ẹniti a o wẹ̀numọ́ nì ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o le mọ́: lẹhin eyinì ni ki o wọ̀ ibudó, ṣugbọn ki o gbé ẹhin ode agọ́ rẹ̀ ni ijọ́ meje.

9 Yio si ṣe ni ijọ́ keje, ni ki o fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro li ori rẹ̀, ati irungbọn rẹ̀, ati ipenpeju rẹ̀, ani gbogbo irun rẹ̀ ni ki o fá kuro: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ pẹlu ninu omi, on o si di mimọ́.

10 Ni ijọ́ kẹjọ ki o mú ọdọ-agutan meji akọ alailabùku wá, ati ọdọ-agutan kan abo ọlọdún kan alailabùku, ati idamẹwa mẹta òṣuwọn deali iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi oróro pò, ati òṣuwọn logu oróro kan.

11 Ki alufa ti o sọ ọ di mimọ́ ki o mú ọkunrin na ti a o sọ di mimọ́, ati nkan wọnni wá, siwaju OLUWA, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ:

12 Ki alufa ki o mú akọ ọdọ-agutan kan, ki o si fi i ru ẹbọ ẹbi, ati òṣuwọn logu oróro, ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA:

13 Ki o si pa akọ ọdọ-agutan na ni ibiti on o gbé pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ ati ẹbọ sisun, ní ibi mimọ́ nì: nitoripe bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ ti jẹ́ ti alufa, bẹ̃ si ni ẹbọ irekọja: mimọ́ julọ ni:

14 Ki alufa ki o si mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi na, ki alufa ki o si fi i si eti ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀:

15 Ki alufa ki o si mú ninu oróro òṣuwọn logu na, ki o si dà a si atẹlẹwọ òsi ara rẹ̀:

16 Ki alufa ki o si tẹ̀ ika rẹ̀ ọtún bọ̀ inu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ òsi rẹ̀, ki o si fi ika rẹ̀ ta ninu oróro na nigba meje niwaju OLUWA:

17 Ati ninu oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ rẹ̀ ni ki alufa ki o fi si etí ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀, lori ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi:

18 Ati oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ alufa ni ki o dà si ori ẹniti a o wẹ̀numọ́: ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA.

19 Ki alufa ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki o si ṣètutu fun ẹniti a o wẹ̀numọ́ kuro ninu aimọ́ rẹ̀; lẹhin eyinì ni ki o pa ẹran ẹbọ sisun.

20 Ki alufa ki o si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ lori pẹpẹ: ki alufa ki o ṣètutu fun u, on o si di mimọ́.

21 Bi o ba si ṣe talaka, ti kò le mú tobẹ̃ wá, njẹ ki o mú akọ ọdọ-agutan kan wá fun ẹbọ ẹbi lati fì, lati ṣètutu fun u, ati ọkan ninu idamẹwa òṣuwọn deali iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ, ati òṣuwọn logu oróro kan;

22 Ati àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji, irú eyiti ọwọ́ rẹ̀ ba to; ki ọkan ki o si ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki ekeji ki o si ṣe ẹbọ sisun.

23 Ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá ni ijọ́ kẹjọ fun ìwẹnumọ́ rẹ̀, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, niwaju OLUWA.

24 Ki alufa ki o si mú ọdọ-agutan ẹbọ ẹbi, ati òṣuwọn logu oróro, ki alufa ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA.

25 Ki o si pa ọdọ-agutan ẹbọ ẹbi, ki alufa ki o si mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi na, ki o si fi i si etí ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀.

26 Ki alufa ki o si dà ninu oróro na si atẹlẹwọ òsi ara rẹ̀:

27 Ki alufa ki o si fi iká rẹ̀ ọtún ta ninu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ òsi rẹ̀ nigba meje niwaju OLUWA:

28 Ki alufa ki o si fi ninu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ rẹ̀ si eti ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀, si ibi ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi:

29 Ati oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ alufa ni ki o fi si ori ẹniti a o wẹ̀numọ́, lati ṣètutu fun u niwaju OLUWA.

30 Ki o si fi ọkan ninu àdaba nì rubọ, tabi ọkan ninu ọmọ ẹiyẹle nì, iru eyiti ọwọ́ rẹ̀ ba to:

31 Ani irú eyiti apa rẹ̀ ka, ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ: ki alufa ki o si ṣètutu fun ẹniti a o wẹ̀numọ́ niwaju OLUWA.

32 Eyi li ofin rẹ̀ li ara ẹniti àrun ẹ̀tẹ wà, apa ẹniti kò le ka ohun ìwẹnumọ́ rẹ̀.

Bí Ara Ògiri Bá Séèébu

33 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,

34 Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ Kenaani, ti mo fi fun nyin ni ilẹ-iní, ti mo ba si fi àrun ẹ̀tẹ sinu ile kan ninu ilẹ-iní nyin;

35 Ti onile na si wá ti o si wi fun alufa pe, O jọ li oju mi bi ẹnipe àrun mbẹ ninu ile na:

36 Nigbana ni ki alufa ki o fun wọn li aṣẹ, ki nwọn ki o kó ohun ile na jade, ki alufa ki o to wọ̀ inu rẹ̀ lọ lati wò àrun na, ki ohun gbogbo ti mbẹ ninu ile na ki o máṣe jẹ́ alaimọ́: lẹhin eyinì ni ki alufa ki o wọ̀ ọ lati wò ile na:

37 Ki o si wò àrun na, si kiyesi i, bi àrun na ba mbẹ lara ogiri ile na pẹlu ìla gbòrogbòro, bi ẹni ṣe bi ọbẹdò tabi pupa rusurusu, ti o jìn li oju jù ogiri lọ;

38 Nigbana ni ki alufa ki o jade ninu ile na si ẹnu-ọ̀na ile na, ki o si há ilẹkun ile na ni ijọ́ meje:

39 Ki alufa ki o tun wá ni ijọ́ keje, ki o si wò o: si kiyesi i, bi àrun na ba ràn lara ogiri ile na;

40 Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ ki nwọn ki o yọ okuta na kuro lara eyiti àrun na gbé wà, ki nwọn ki o si kó wọn lọ si ibi aimọ́ kan lẹhin ilu na:

41 Ki o si mu ki nwọn ki o ha inu ile na yiká kiri, ki nwọn ki o kó erupẹ ti a ha nì kuro lọ si ẹhin ilu na si ibi aimọ́ kan:

42 Ki nwọn ki o si mú okuta miran, ki nwọn ki o si fi i di ipò okuta wọnni, ki nwọn ki o si mú ọrọ miran ki nwọn ki o si fi rẹ́ ile na.

43 Bi àrùn na ba si tun pada wá, ti o si tun sọ jade ninu ile na, lẹhin igbati nwọn ba yọ okuta wọnni kuro, ati lẹhin igbati nwọn ba ha ile na, ati lẹhin igbati nwọn ba rẹ́ ẹ;

44 Nigbana ni ki alufa ki o wá, ki o wò o, si kiyesi i, bi àrun ba ràn si i ninu ile na, ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni mbẹ ninu ile na: aimọ́ ni.

45 Ki o si wó ile na, okuta rẹ̀, ati ìti igi rẹ̀, ati gbogbo erupẹ ile na; ki o si kó wọn jade kuro ninu ilu na lọ si ibi aimọ́ kan.

46 Ẹniti o ba si wọ̀ ile na ni gbogbo ìgba na ti a sé e mọ́, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

47 Ẹniti o ba dubulẹ ninu ile na ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀: ẹniti o jẹun ninu ile na ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀.

48 Ati bi alufa ba wọ̀ ile, ti o si wò o, si kiyesi i, ti àrun inu ile na kò ba ràn si i, lẹhin igbati a rẹ́ ile na tán; nigbana ni ki alufa ki o pè ile na ni mimọ́, nitoripe àrun na ti jiná.

49 Ki o si mú ẹiyẹ meji, ati igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu wá, lati wẹ̀ ile na mọ́:

50 Ki o si pa ọkan ninu ẹiyẹ na, ninu ohunèlo amọ loju omi ti nṣàn:

51 Ki o si mú igi opepe, ati ewe-hissopu, ati ododó, ati ẹiyẹ alãye nì, ki o si tẹ̀ wọn bọ̀ inu ẹ̀jẹ ẹiyẹ ti a pa nì, ati ninu omi ṣiṣàn nì, ki o si fi wọ́n ile na nigba meje:

52 Ki o si fi ẹ̀jẹ ẹiyẹ na wẹ̀ ile na mọ́, ati pẹlu omi ṣiṣàn nì, ati pẹlu ẹiyẹ alãye nì, ati pẹlu igi opepe nì, ati pẹlu ewe-hissopu nì, ati pẹlu ododó:

53 Ṣugbọn ki o jọwọ ẹiyẹ alãye nì lọwọ lọ kuro ninu ilu lọ sinu gbangba oko, ki o si ṣètutu si ile na: yio si di mimọ́.

54 Eyi li ofin fun gbogbo onirũru àrun ẹ̀tẹ, ati ipẹ́;

55 Ati fun ẹ̀tẹ aṣọ, ati ti ile;

56 Ati fun wiwu, ati fun apá, ati fun àmi didán:

57 Lati kọni nigbati o ṣe alaimọ́, ati nigbati o ṣe mimọ́: eyi li ofin ẹ̀tẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27