Lef 18 YCE

Àwọn Èèwọ̀ tí Ó Jẹmọ́ Bíbá Obinrin Lòpọ̀

1 OLUWA si sọ fun Mose pe,

2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

3 Ẹnyin kò gbọdọ hùwa bi ìwa ilẹ Egipti nibiti ẹnyin ti ngbé: ẹnyin kò si gbọdọ hùwa ìwa ilẹ Kenaani, nibiti emi o mú nyin lọ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ rìn nipa ìlana wọn.

4 Ki ẹnyin ki o ma ṣe ofin mi, ki ẹnyin si ma pa ìlana mi mọ́, lati ma rìn ninu wọn: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

5 Ẹnyin o si ma pa ìlana mi mọ́, ati ofin mi: eyiti bi enia ba ṣe, on o ma yè ninu wọn: Emi li OLUWA.

6 Ẹnikẹni kò gbọdọ sunmọ ẹnikan ti iṣe ibatan rẹ̀ lati tú ìhoho rẹ̀: Emi li OLUWA.

7 Ihoho baba rẹ, tabi ìhoho iya rẹ̀, ni iwọ kò gbọdọ tú: iya rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.

8 Ihoho aya baba rẹ ni iwọ kò gbọdọ tú: ìhoho baba rẹ ni.

9 Ihoho arabinrin rẹ, ọmọ baba rẹ, tabi ọmọ iya rẹ, ti a bi ni ile, tabi ti a bi li ode, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú.

10 Ìhoho ọmọbinrin ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ti ọmọbinrin ọmọ rẹ obinrin, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú: nitoripe ìhoho ara rẹ ni nwọn.

11 Ìhoho ọmọbinrin aya baba rẹ, ti a bi lati inu baba rẹ wá, arabinrin rẹ ni, iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.

12 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin baba rẹ: ibatan baba rẹ ni.

13 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin iya rẹ: nitoripe ibatan iya rẹ ni.

14 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arakunrin baba rẹ, iwọ kò gbọdọ sunmọ aya rẹ̀: arabinrin baba rẹ ni.

15 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya ọmọ rẹ: nitoripe aya ọmọ rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.

16 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya arakunrin rẹ: ìhoho arakunrin rẹ ni.

17 Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho obinrin ati ti ọmọbinrin rẹ̀; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ obinrin, lati tú ìhoho wọn; nitoripe ibatan ni nwọn: ohun buburu ni.

18 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ́ arabinrin aya rẹ li aya, lati bà a ninu jẹ́, lati tú ìhoho rẹ̀, pẹlu rẹ̀ nigbati o wà lãye.

19 Ati pẹlu iwọ kò gbọdọ sunmọ obinrin kan lati tú u ni ìhoho, ni ìwọn igbati a yà a sapakan nitori aimọ́ rẹ̀.

20 Pẹlupẹlu iwọ kò gbọdọ bá aya ẹnikeji rẹ dàpọ lati bà ara rẹ jẹ́ pẹlu rẹ̀.

21 Iwọ kò si gbọdọ fi irú-ọmọ rẹ kan fun Moleki, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA.

22 Iwọ kò gbọdọ bá ọkunrin dápọ bi obinrin: irira ni.

23 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bá ẹranko kan dàpọ, lati fi i bà ara rẹ jẹ́: bẹ̃ni obinrin kan kò gbọdọ duro niwaju ẹranko kan lati dubulẹ tì i: idaru-dàpọ ni.

24 Ẹ máṣe bà ara nyin jẹ́ ninu gbogbo nkan wọnyi: nitoripe ninu gbogbo nkan wọnyi li awọn orilẹ-ède, ti mo lé jade niwaju nyin dibajẹ́:

25 Ilẹ na si dibajẹ́: nitorina ni mo ṣe bẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wò lori rẹ̀, ilẹ tikararẹ̀ si bì awọn olugbé rẹ̀ jade.

26 Nitorina ni ki ẹnyin ki o ṣe ma pa ìlana ati ofin mi mọ́, ki ẹnyin ki o máṣe ṣe ọkan ninu irira wọnyi; tabi ẹnikan ninu ibilẹ nyin, tabi alejò ti nṣe atipo ninu nyin:

27 Nitoripe gbogbo irira wọnyi li awọn ọkunrin ilẹ na ṣe, ti o ti wà ṣaju nyin, ilẹ na si dibajẹ́;

28 Ki ilẹ na ki o má ba bì nyin jade pẹlu, nigbati ẹnyin ba bà a jẹ́, bi o ti bì awọn orilẹ-ède jade, ti o ti wà ṣaju nyin.

29 Nitoripe ẹnikẹni ti o ba ṣe ọkan ninu irira wọnyi, ani ọkàn wọnni ti o ba ṣe wọn li a o ke kuro lãrin awọn enia wọn.

30 Nitorina ni ki ẹnyin ki o pa aṣẹ mi mọ́, ki ẹnyin ki o máṣe ọkan ninu irira wọnyi, ti nwọn ti ṣe ṣaju nyin, ki ẹnyin ki o má si bà ara nyin jẹ́ ninu rẹ̀: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27