Lef 27 YCE

Àwọn Òfin tí Ó Jẹmọ́ Ohun tí a fi fún OLUWA

1 OLUWA si sọ fun Mose pe,

2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati enia kan ba jẹ́ ẹjẹ́ pataki kan, ki awọn enia na ki o jẹ́ ti OLUWA gẹgẹ bi idiyelé rẹ.

3 Idiyelé rẹ fun ọkunrin yio si jẹ́ lati ẹni ogún ọdún lọ titi di ọgọta ọdún, idiyelé rẹ yio si jẹ́ ãdọta ṣekeli fadakà, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́.

4 Bi on ba si ṣe obinrin, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ọgbọ̀n ṣekeli.

5 Bi o ba si ṣepe lati ọmọ ọdún marun lọ, titi di ẹni ogún ọdún, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ogún ṣekeli fun ọkunrin, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa.

6 Bi o ba si ṣepe lati ọmọ oṣù kan lọ titi di ọmọ ọdún marun, njẹ ki idiyelé rẹ fun ọkunrin ki o jẹ́ ṣekeli fadakà marun, ati fun obinrin, idiyelé rẹ yio jẹ ṣekeli fadakà mẹta.

7 Bi o ba si ṣe lati ẹni ọgọta ọdún lọ tabi jù bẹ̃ lọ; bi o ba jẹ́ ọkunrin, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ṣekeli mẹdogun, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa.

8 Ṣugbọn bi on ba ṣe talakà jù idiyele lọ, njẹ ki o lọ siwaju alufa, ki alufa ki o diyelé e; gẹgẹ bi agbara ẹniti o jẹ́ ẹjẹ́ na ni ki alufa ki o diyelé e.

9 Bi o ba si ṣepe ẹran ni, ninu eyiti enia mú ọrẹ-ẹbọ tọ̀ OLUWA wá, gbogbo eyiti ẹnikẹni ba múwa ninu irú nkan wọnni fun OLUWA ki o jẹ́ mimọ́.

10 On kò gbọdọ pa a dà, bẹ̃ni kò gbọdọ pàrọ rẹ̀, rere fun buburu, tabi buburu fun rere: bi o ba ṣepe yio pàrọ rẹ̀ rára, ẹran fun ẹran, njẹ on ati ipàrọ rẹ̀ yio si jẹ́ mimọ́.

11 Bi o ba si ṣepe ẹran alaimọ́ kan ni, ninu eyiti nwọn kò mú rubọ si OLUWA, njẹ ki o mú ẹran na wá siwaju alufa:

12 Ki alufa ki o si diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi iwọ alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri.

13 Ṣugbọn bi o ba fẹ́ rà a pada rára, njẹ ki o fi idamarun rẹ̀ kún idiyelé rẹ.

14 Bi enia kan yio ba si yà ile rẹ̀ sọtọ̀ lati jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, njẹ ki alufa ki o diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri.

15 Ati bi ẹniti o yà a sọ̀tọ ba nfẹ́ rà ile rẹ̀ pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ̀ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀.

16 Bi enia kan ba si nfẹ́ yà ninu oko ti o jogún sọ̀tọ fun OLUWA, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ bi irugbìn rẹ̀: òṣuwọn homeri irugbìn barle kan ãdọta ṣekeli fadakà.

17 Bi o ba yà oko rẹ̀ sọ̀tọ lati ọdún jubeli wá, gẹgẹ bi idiyelé rẹ bẹ̃ni ki o ri.

18 Ṣugbọn bi o ba yà oko rẹ̀ sọtọ̀ lẹhin ọdún jubeli, njẹ ki alufa ki o ṣìro owo rẹ̀ fun u, gẹgẹ bi ìwọn ọdún ti o kù, titi di ọdún jubeli, a o si din i kù ninu idiyelé rẹ.

19 Ati bi ẹniti o yà oko na sọtọ̀ ba fẹ́ rà a pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀.

20 Bi on kò ba si fẹ́ rà oko na pada, tabi bi o ba ti tà oko na fun ẹlomiran, ki a máṣe rà a pada mọ́.

21 Ṣugbọn oko na, nigbati o ba yọ li ọdún jubeli, ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, bi oko ìya-sọtọ; iní rẹ̀ yio jẹ́ ti alufa.

22 Ati bi ẹnikan ba yà oko kan sọ̀tọ fun OLUWA ti on ti rà, ti ki iṣe ninu oko ti o jogún;

23 Njẹ ki alufa ki o ṣìro iye idiyelé rẹ̀ fun u, titi di ọdún jubeli: ki on ki o si fi idiyelé rẹ li ọjọ́ na, bi ohun mimọ́ fun OLUWA.

24 Li ọdún jubeli ni ki oko na ki o pada sọdọ ẹniti o rà a, ani sọdọ rẹ̀ ti ẹniti ini ilẹ na iṣe.

25 Ki gbogbo idiyelé rẹ ki o si jẹ́ gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́: ogún gera ni ṣekeli kan.

26 Kìki akọ́bi ẹran, ti iṣe akọ́bi ti OLUWA, li ẹnikan kò gbọdọ yàsọtọ; ibaṣe akọmalu, tabi agutan: ti OLUWA ni.

27 Bi o ba ṣe ti ẹran alaimọ́ ni, njẹ ki o gbà a silẹ gẹgẹ bi idiyelé rẹ, ki o si fi idamarun rẹ̀ kún u: tabi bi kò ba si rà a pada, njẹ ki a tà a, gẹgẹ bi idiyelé rẹ.

28 Ṣugbọn kò sí ohun ìyasọtọ kan, ti enia ba yàsọtọ fun OLUWA ninu ohun gbogbo ti o ní, ati enia, ati ẹran, ati ilẹ-iní rẹ̀, ti a gbọdọ tà tabi ti a gbọdọ rà pada: ohun gbogbo ti a ba yàsọtọ mimọ́ julọ ni si OLUWA.

29 Kò sí ẹni ìyasọtọ ti a ba yàsọtọ ninu enia, ti a le gbàsilẹ; pipa ni ki a pa a.

30 Ati gbogbo idamẹwa ilẹ na ibaṣe ti irugbìn ilẹ na, tabi ti eso igi, ti OLUWA ni: mimọ́ ni fun OLUWA.

31 Bi o ba ṣepe enia ba ràpada rára ninu ohun idamẹwa rẹ̀, ki o si fi idamarun kún u.

32 Ati gbogbo idamẹwa ọwọ́ ẹran, tabi ti agbo-ẹran, ani ohunkohun ti o ba kọja labẹ ọpá, ki ẹkẹwa ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA.

33 Ki o máṣe yẹ̀ ẹ wò bi o jẹ́ rere tabi buburu, bẹ̃li on kò gbọdọ pàrọ rẹ̀: bi o ba si ṣepe o pàrọ rẹ̀ rára, njẹ ati on ati ipàrọ rẹ̀ yio jẹ́ mimọ́; a kò gbọdọ rà a pada.

34 Wọnyi li ofin, ti OLUWA palaṣẹ fun Mose fun awọn ọmọ Israeli li òke Sinai.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27