Num 1 YCE

1 OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, ninu agọ́ ajọ, li ọjọ́ kini oṣù keji, li ọdún keji, ti nwọn jade lati ilẹ Egipti wá, wipe,

2 Ẹ kaye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, olukuluku ọkunrin, nipa ori wọn;

3 Lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli, iwọ ati Aaroni ni ki o kaye wọn gẹgẹ bi ogun wọn.

4 Ki ọkunrin kọkan lati inu olukuluku ẹ̀ya ki o si wà pẹlu nyin; ki olukuluku jẹ́ olori ile awọn baba rẹ̀.

5 Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin na ti yio duro pẹlu nyin: ti Reubeni; Elisuri ọmọ Ṣedeuri.

6 Ti Simeoni; Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.

7 Ti Juda; Naṣoni ọmọ Amminadabu.

8 Ti Issakari; Netaneli ọmọ Suari.

9 Ti Sebuluni; Eliabu ọmọ Heloni.

10 Ti awọn ọmọ Josefu: ti Efraimu; Elliṣama ọmọ Ammihudu: ti Manasse; Gamalieli ọmọ Pedasuru.

11 Ti Benjamini; Abidani ọmọ Gideoni.

12 Ti Dani; Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.

13 Ti Aṣeri; Pagieli ọmọ Okanri.

14 Ti Gadi; Eliasafu ọmọ Deueli.

15 Ti Naftali; Ahira ọmọ Enani.

16 Wọnyi li awọn ti a yàn ninu ijọ, olori ẹ̀ya awọn baba wọn, awọn olori ẹgbẹgbẹrun ni Israeli.

17 Ati Mose ati Aaroni mú awọn ọkunrin wọnyi ti a pè li orukọ:

18 Nwọn si pè gbogbo ijọ enia pọ̀ li ọjọ́ kini oṣù keji, nwọn si pìtan iran wọn gẹgẹ bi idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, nipa ori wọn.

19 Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li o si kaye wọn ni ijù Sinai.

20 Ati awọn ọmọ Reubeni, akọ́bi Israeli, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, nipa ori wọn, gbogbo ọkunrin lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

21 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Reubeni, o jẹ́ ẹgba mẹtalelogun o le ẹdẹgbẹta.

22 Ti awọn ọmọ Simeoni, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, nipa ori wọn, gbogbo ọkunrin lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

23 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Simeoni, o jẹ́ ẹgba mọkandilọgbọ̀n o le ẹdegbeje.

24 Ti awọn ọmọ Gadi, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

25 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Gadi, o jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ãdọtalelẹgbẹjọ.

26 Ti awọn ọmọ Juda, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

27 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Juda, o jẹ́ ẹgbã mẹtadilogoji o le ẹgbẹ̀ta.

28 Ti awọn ọmọ Issakari, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

29 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Issakari, o jẹ́ ẹgbã mẹtadilọgbọ̀n o le irinwo.

30 Ti awọn ọmọ Sebuluni, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

31 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Sebuluni, o jẹ́ ẹgbã mejidilọgbọ̀n o le egbeje.

32 Ti awọn ọmọ Josefu, eyinì ni, ti awọn ọmọ Efraimu, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

33 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Efraimu, o jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta.

34 Ti awọn ọmọ Manasse, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

35 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Manasse, o jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le igba.

36 Ti awọn ọmọ Benjamini, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

37 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Benjamini, o jẹ́ ẹgba mẹtadilogun o le egbeje.

38 Ti awọn ọmọ Dani, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

39 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Dani, o jẹ́ ẹgbã mọkanlelọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin.

40 Ti awọn ọmọ Aṣeri, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

41 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Aṣeri, o jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹjọ.

42 Ti awọn ọmọ Naftali, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;

43 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Naftali, o jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje.

44 Wọnyi li awọn ti a kà, ti Mose ati Aaroni kà, ati awọn olori Israeli, ọkunrin mejila: olukuluku wà fun ile awọn baba rẹ̀.

45 Bẹ̃ni gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Israeli, nipa ile baba wọn, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli;

46 Ani gbogbo awọn ti a kà o jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ enia o le egbejidilogun din ãdọta.

47 Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ẹ̀ya baba wọn li a kò kà mọ́ wọn.

48 Nitoripe OLUWA ti sọ fun Mose pe,

49 Kìki ẹ̀ya Lefi ni ki iwọ ki o máṣe kà, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe kà iye wọn mọ́ awọn ọmọ Israeli.

50 Ṣugbọn ki iwọ ki o yàn awọn ọmọ Lefi sori agọ́ érí, ati sori gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati sori ohun gbogbo ti iṣe tirẹ̀: awọn ni ki o ma rù agọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀; awọn ni yio si ma ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀, ki nwọn ki o si dó yi agọ́ na ká.

51 Nigbati agọ́ na ba si ṣí siwaju, ki awọn ọmọ Lefi ki o tú u palẹ: nigbati nwọn o ba si pa agọ́ na, awọn ọmọ Lefi ni ki o gbé e duro: alejó ti o ba sunmọtosi, pipa ni.

52 Ki awọn ọmọ Israeli ki o si pa agọ́ wọn, olukuluku ni ibudó rẹ̀, ati olukuluku lẹba ọpagun rẹ̀, gẹgẹ bi ogun wọn.

53 Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o dó yi agọ́ erí na ká, ki ibinu ki o má ba si lara ijọ awọn ọmọ Israeli: ki awọn ọmọ Lefi ki o si ma ṣe itọju agọ́ ẹrí na.

54 Bayi ni awọn ọmọ Israeli si ṣe; gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃ni nwọn ṣe.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36