Num 34 YCE

Àwọn Ààlà Ilẹ̀ náà

1 OLUWA si sọ fun Mose pe,

2 Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ Kenaani, (eyi ni ilẹ ti yio bọ́ si nyin lọwọ ni iní, ani ilẹ Kenaani gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀,)

3 Njẹ ki ìha gusù nyin ki o jẹ́ ati aginjù Sini lọ titi dé ẹba Edomu, ati opinlẹ gusù nyin ki o jẹ́ lati opin Okun Iyọ̀ si ìha ìla-õrùn:

4 Ki opinlẹ nyin ki o si yí lati gusù wá si ìgoke Akrabbimu, ki o si kọja lọ si Sini: ati ijadelọ rẹ̀ ki o jẹ́ ati gusù lọ si Kadeṣi-barnea, ki o si dé Hasari-addari, ki o si kọja si Asmoni:

5 Ki opinlẹ rẹ̀ ki o si yiká lati Asmoni lọ dé odò Egipti, okun ni yio si jẹ́ opin rẹ̀.

6 Ati opinlẹ ìha ìwọ-õrùn, ani okun nla ni yio jẹ́ opin fun nyin: eyi ni yio jẹ́ opinlẹ ìha ìwọ-õrùn fun nyin.

7 Eyi ni yio si jẹ́ opinlẹ ìha ariwa fun nyin: lati okun nla lọ ki ẹnyin ki o fi ori sọ òke Hori:

8 Lati òke Hori lọ ki ẹnyin ki o fi ori sọ ati wọ̀ Hamati; ijadelọ opinlẹ na yio si jẹ́ Sedadi:

9 Opinlẹ rẹ yio si dé Sifroni, ati ijadelọ rẹ̀ yio dé Hasari-enani: eyi ni yio jẹ́ opinlẹ ìha ariwa nyin.

10 Ki ẹnyin ki o si sàmi si opinlẹ nyin ni ìha ìla-õrùn lati Hasari-enani lọ dé Ṣefamu:

11 Ki opinlẹ na ki o si ti Ṣefamu sọkalẹ lọ si Ribla, ni ìha ìla-õrùn Aini; ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ, ki o si dé ìha okun Kinnereti ni ìha ìla-õrùn.

12 Ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ si Jordani, ijadelọ rẹ̀ yio jẹ Okun Iyọ̀: eyi ni yio jẹ́ ilẹ nyin gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀ yiká kiri.

13 Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, wipe, Eyi ni ilẹ na ti ẹnyin o fi keké gbà ni iní, ti OLUWA paṣẹ lati fi fun ẹ̀ya mẹsan, ati àbọ ẹ̀ya nì:

14 Fun ẹ̀ya awọn ọmọ Reubeni gẹgẹ bi ile baba wọn, ati ẹ̀ya awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi ile baba wọn ti gbà; àbọ ẹ̀ya Manasse si ti gbà, ipín wọn:

15 Ẹ̀ya mejẽji ati àbọ ẹ̀ya nì ti gbà ipín wọn ni ìha ihin Jordani leti Jeriko, ni ìha gabasi, ni ìha ìla-õrùn.

Àwọn Olórí tí Yóo Pín Ilẹ̀ náà

16 OLUWA si sọ fun Mose pe,

17 Wọnyi li orukọ awọn ọkunrin ti yio pín ilẹ na fun nyin: Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni.

18 Ki ẹnyin ki o si mú olori kan ninu ẹ̀ya kọkan, lati pín ilẹ na ni iní.

19 Orukọ awọn ọkunrin na si ni wọnyi: ni ẹ̀ya Juda, Kalebu ọmọ Jefunne.

20 Ati ni ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni, Ṣemueli ọmọ Ammihudu.

21 Ni ẹ̀ya Benjamini, Elidadi ọmọ Kisloni.

22 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Dani, Bukki ọmọ Jogli.

23 Olori awọn ọmọ Josefu: ni ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse, Hannieli ọmọ Efodu:

24 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Efraimu, Kemueli ọmọ Ṣiftani.

25 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Sebuluni, Elisafani ọmọ Parnaki.

26 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari, Paltieli ọmọ Assani.

27 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri, Ahihudu ọmọ Ṣelomi.

28 Ati olori ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali, Pedaheli ọmọ Ammihudu.

29 Awọn wọnyi li ẹniti OLUWA paṣẹ fun lati pín iní na fun awọn ọmọ Israeli ni ilẹ Kenaani.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36