Num 6 YCE

Òfin fún Àwọn Nasiri

1 OLUWA si sọ fun Mose pe,

2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ọkunrin kan tabi obinrin kan ba yà ara wọn sapakan lati ṣe ileri ti Nasiri, lati yà ara wọn si OLUWA:

3 Ki o yà ara rẹ̀ kuro ninu ọti-waini tabi ọti lile; ki o má si ṣe mu ọti-waini kikan, tabi ọti lile ti o kan, ki o má si ṣe mu ọti eso-àjara kan, bẹ̃ni kò gbọdọ jẹ eso-àjara tutù tabi gbigbẹ.

4 Ni gbogbo ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ ni ki o gbọdọ jẹ ohun kan ti a fi eso-àjara ṣe, lati kóro rẹ̀ titi dé ẽpo rẹ̀.

5 Ni gbogbo ọjọ́ ileri ìyasapakan rẹ̀, ki abẹ kan máṣe kàn a li ori: titi ọjọ́ wọnni yio fi pé, ninu eyiti o yà ara rẹ̀ si OLUWA, ki o jẹ́ mimọ́, ki o si jẹ ki ìdi irun ori rẹ̀ ki o ma dàgba.

6 Ni gbogbo ọjọ́ ti o yà ara rẹ̀ si OLUWA, on kò gbọdọ sunmọ okú.

7 On kò gbọdọ sọ ara rẹ̀ di alaimọ́ nitori baba rẹ̀, tabi nitori iya rẹ̀, nitori arakunrin rẹ̀, tabi nitori arabinrin rẹ̀, nigbati nwọn ba kú: nitoripe ìyasapakan Ọlọrun rẹ̀ mbẹ li ori rẹ̀.

8 Ni gbogbo ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀, mimọ́ li on fun OLUWA.

9 Bi enia kan ba si kú lojiji lẹba ọdọ rẹ̀, ti o ba si bà ori ìyasapakan rẹ̀ jẹ́; nigbana ni ki o fá ori rẹ̀ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀, ni ijọ́ keje ni ki o fá a.

10 Ati ni ijọ́ kẹjọ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ:

11 Ki alufa ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun, ki o si ṣètutu fun u, nitoriti o ṣẹ̀ nipa okú, ki o si yà ori rẹ̀ simimọ́ li ọjọ́ na.

12 Ki o si yà ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ simimọ́ si OLUWA, ki o si mú akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹbi: ṣugbọn ọjọ́ ti o ti ṣaju yio di asan, nitoripe ìyasapakan rẹ̀ bàjẹ́.

13 Eyi si li ofin ti Nasiri, nigbati ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ ba pé: ki a si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ:

14 On o si mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá fun OLUWA, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan alailabùkun fun ẹbọ sisun, ati abo ọdọ-agutan kan ọlọdún kan alailabùkun fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan alailabùkun fun ẹbọ alafia.

15 Ati agbọ̀n àkara alaiwu kan, àkara adidùn iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si, ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn.

16 Ki alufa ki o mú wọn wá siwaju OLUWA, ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ati ẹbọ sisun rẹ̀:

17 Ki o si ru àgbo na li ẹbọ alafia si OLUWA, pẹlu agbọ̀n àkara alaiwu: ki alufa pẹlu ki o si ru ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.

18 Ki Nasiri na ki o fá ori ìyasapakan rẹ̀ li ẹnu-ọ̀na agọ́ àjọ, ki o si mú irun ori ìyasapakan rẹ̀ ki o si fi i sinu iná ti mbẹ labẹ ẹbọ alafia na.

19 Ki alufa ki o si mú apá bibọ̀ àgbo na, ati àkara adidùn kan alaiwu kuro ninu agbọ̀n na, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan alaiwu, ki o si fi wọn lé ọwọ́ Nasiri na, lẹhin ìgba ti a fá irun ori ìyasapakan rẹ̀ tán:

20 Ki alufa ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: mimọ́ li eyi fun alufa na, pẹlu àiya fifì, ati itan agbesọsoke: lẹhin na Nasiri na le ma mu ọti-waini.

21 Eyi li ofin ti Nasiri ti o ṣe ileri, ati ti ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ si OLUWA fun ìyasapakan rẹ̀ li àika eyiti ọwọ́ on le tẹ̀: gẹgẹ bi ileri ti o ṣe, bẹ̃ni ki o ṣe nipa ofin ìyasapakan rẹ̀.

Ibukun Àlùfáà

22 OLUWA si sọ fun Mose pe,

23 Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Bayi li ẹnyin o ma sure fun awọn ọmọ Israeli; ki ẹ ma wi fun wọn pe,

24 Ki OLUWA ki o busi i fun ọ, ki o si pa ọ mọ́:

25 Ki OLUWA ki o mu oju rẹ̀ mọlẹ si ọ lara, ki o si ṣãnu fun ọ:

26 Ki OLUWA ki o ma bojuwò ọ, ki o si ma fun ọ ni alafia.

27 Bayi ni nwọn o fi orukọ mi sara awọn ọmọ Israeli; emi o si busi i fun wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36