Num 33 YCE

Ìrìn Àjò láti Ijipti sí Moabu

1 WỌNYI ni ìrin awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá pẹlu awọn ogun wọn, nipa ọwọ́ Mose ati Aaroni.

2 Mose si kọwe ijadelọ wọn gẹgẹ bi ìrin wọn, nipa aṣẹ OLUWA; wọnyi si ni ìrin wọn gẹgẹ bi ijadelọ wọn.

3 Nwọn si ṣí kuro ni Ramesesi li oṣù kini, ni ijọ́ kẹdogun oṣù kini na; ni ijọ́ keji ajọ irekọja li awọn ọmọ Israeli jade pẹlu ọwọ́ giga li oju gbogbo awọn ara Egipti.

4 Bi awọn ara Egipti ti nsinkú gbogbo awọn akọ́bi wọn ti OLUWA kọlù ninu wọn: lara awọn oriṣa wọn pẹlu li OLUWA ṣe idajọ.

5 Awọn ọmọ Israeli si ṣí kuro ni Ramesesi, nwọn si dó si Sukkotu.

6 Nwọn si ṣí kuro ni Sukkotu, nwọn si dó si Etamu, ti mbẹ leti aginjù.

7 Nwọn si ṣí kuro ni Etamu, nwọn si pada lọ si Pi-hahirotu, ti mbẹ niwaju Baali-sefoni: nwọn si dó siwaju Migdolu.

8 Nwọn si ṣí kuro niwaju Hahirotu, nwọn si là ãrin okun já lọ si aginjù: nwọn si rìn ìrin ijọ́ mẹta li aginjù Etamu, nwọn si dó si Mara.

9 Nwọn si ṣí kuro ni Mara, nwọn si wá si Elimu: ni Elimu ni orisun omi mejila, ati ãdọrin igi ọpẹ wà; nwọn si dó sibẹ̀.

10 Nwọn si ṣí kuro ni Elimu, nwọn si dó si ẹba Okun Pupa.

11 Nwọn si ṣí kuro li Okun Pupa, nwọn si dó si aginjù Sini.

12 Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sini, nwọn si dó si Dofka.

13 Nwọn si ṣí kuro ni Dofka, nwọn si dó si Aluṣi.

14 Nwọn si ṣí kuro ni Aluṣi, nwọn si dó si Refidimu, nibiti omi kò gbé sí fun awọn enia na lati mu.

15 Nwọn si ṣí kuro ni Refidimu, nwọn si dó si aginjù Sinai.

16 Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sinai, nwọn si dó si Kibrotu-hattaafa.

17 Nwọn si ṣí kuro ni Kibrotu-hattaafa, nwọn si dó si Haserotu.

18 Nwọn si ṣí kuro ni Haserotu, nwọn si dó si Ritma.

19 Nwọn si ṣí kuro ni Ritma, nwọn si dó si Rimmon-peresi.

20 Nwọn si ṣí kuro ni Rimmon-peresi, nwọn si dó si Libna.

21 Nwọn si ṣí kuro ni Libna, nwọn si dó si Rissa.

22 Nwọn si ṣí kuro ni Rissa, nwọn si dó si Kehelata.

23 Nwọn si ṣí kuro ni Kehelata, nwọn si dó si òke Ṣeferi.

24 Nwọn si ṣí kuro ni òke Ṣeferi, nwọn si dó si Harada.

25 Nwọn si ṣí kuro ni Harada, nwọn si dó si Makhelotu.

26 Nwọn si ṣí kuro ni Makhelotu, nwọn si dó si Tahati.

27 Nwọn si ṣí kuro ni Tahati, nwọn si dó si Tera.

28 Nwọn si ṣí kuro ni Tera, nwọn si dó si Mitka.

29 Nwọn si ṣí kuro ni Mitka, nwọn si dó si Haṣmona.

30 Nwọn si ṣí kuro ni Haṣmona, nwọn si dó si Moserotu.

31 Nwọn si ṣí kuro ni Moserotu, nwọn si dó si Bene-jaakani.

32 Nwọn si ṣí kuro ni Bene-jaakani, nwọn si dó si Hori-haggidgadi.

33 Nwọn si ṣí kuro ni Hori-haggidgadi, nwọn si dó si Jotbata.

34 Nwọn si ṣí kuro ni Jotbata, nwọn si dó si Abrona.

35 Nwọn si ṣí kuro ni Abrona, nwọn si dó si Esion-geberi.

36 Nwọn si ṣí kuro ni Esion-geberi, nwọn si dó si aginjù Sini, (ti ṣe Kadeṣi),

37 Nwọn si ṣí kuro ni Kadeṣi, nwọn si dó si òke Hori, leti ilẹ Edomu.

38 Aaroni alufa si gùn òke Hori lọ nipa aṣẹ OLUWA, o si kú nibẹ̀, li ogoji ọdún lẹhin ti awọn ọmọ Israeli ti ilẹ Egipti jade wá, li ọjọ́ kini oṣù karun.

39 Aaroni si jẹ́ ẹni ọgọfa ọdún o le mẹta nigbati o kú li òke Hori.

40 Ara Kenaani, ọba Aradi, ti ngbé ìha gusù ni ilẹ Kenaani, o gburó pe awọn ọmọ Israeli mbọ̀.

41 Nwọn si ṣí kuro ni òke Hori, nwọn si dó si Salmona.

42 Nwọn si ṣí ni Salmona, nwọn si dó si Punoni.

43 Nwọn si ṣí kuro ni Punoni, nwọn si dó si Obotu.

44 Nwọn si ṣí kuro ni Obotu, nwọn si dó si Iye-abarimu, li àgbegbe Moabu.

45 Nwọn si ṣí kuro ni Iyimu, nwọn si dó si Dibon-gadi.

46 Nwọn si ṣí kuro ni Dibon-gadi, nwọn si dó si Almon-diblataimu.

47 Nwọn si ṣí kuro ni Almon-diblataimu, nwọn si dó si òke Abarimu, niwaju Nebo.

48 Nwọn si ṣí kuro ni òke Abarimu, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko.

49 Nwọn si dó si ẹba Jordani, lati Beti-jeṣimotu titi dé Abeli-ṣittimu ni pẹtẹlẹ̀ Moabu.

Ìlànà Nípa Líla Odò Jọdani Kọjá

50 OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe,

51 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke odò Jordani si ilẹ Kenaani:

52 Nigbana ni ki ẹnyin ki o lé gbogbo awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; ki ẹnyin si run gbogbo aworán wọn, ki ẹnyin si run gbogbo ere didà wọn, ki ẹnyin si wó gbogbo ibi giga wọn palẹ:

53 Ki ẹnyin ki o si gbà ilẹ na, ki ẹnyin ki o si ma gbé inu rẹ̀: nitoripe mo ti fi ilẹ na fun nyin lati ní i.

54 Ki ẹnyin ki o si fi keké pín ilẹ na ni iní fun awọn idile nyin; fun ọ̀pọ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun diẹ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní diẹ fun: ki ilẹ-iní olukuluku ki o jẹ́ ibiti keké rẹ̀ ba bọ́ si; gẹgẹ bi ẹ̀ya awọn baba nyin ni ki ẹnyin ki o ní i.

55 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba lé awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; yio si ṣe, awọn ti ẹnyin jẹ ki o kù ninu wọn yio di ẹgún si oju nyin, ati ẹgún si nyin ni ìha, nwọn o si ma yọ nyin lẹnu ni ilẹ na, ninu eyiti ẹnyin ngbé.

56 Yio si ṣe, bi emi ti rò lati ṣe si wọn, bẹ̃ni emi o ṣe si nyin.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36