1 OLUWA si sọ fun Mose pe,
2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si gbà ọpá kọkan lọwọ wọn, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, lọwọ gbogbo awọn olori wọn gẹgẹ bi ile awọn baba wọn ọpá mejila: ki o si kọ́ orukọ olukuluku si ara ọpá rẹ̀.
3 Ki o si kọ orukọ Aaroni sara ọpá Lefi: nitoripe ọpá kan yio jẹ́ fun ori ile awọn baba wọn.
4 Ki o si fi wọn lelẹ ninu agọ́ ajọ, niwaju ẹrí, nibiti emi o gbé pade nyin.
5 Yio si ṣe, ọpá ẹniti emi o yàn yio ruwe: emi o si da kikùn awọn ọmọ Israeli duro kuro lọdọ mi, ti nwọn nkùn si nyin.
6 Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli, gbogbo awọn olori wọn si fun u li ọpá, ọpá kan fun olori kan, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, ani ọpá mejila: ọpá Aaroni si wà ninu ọpá wọn.
7 Mose si fi ọpá wọnni lelẹ niwaju OLUWA ninu agọ́ ẹrí.
8 O si ṣe, ni ijọ́ keji ti Mose wọ̀ inu agọ́ ẹrí lọ; si kiyesi i, ọpá Aaroni fun ile Lefi rudi, o si tú, o si tanna, o si so eso almondi.
9 Mose si kó gbogbo ọpá na lati iwaju OLUWA jade tọ̀ gbogbo awọn ọmọ Israeli wá: nwọn si wò, olukuluku si mú ọpá tirẹ̀.
10 OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú ọpá Aaroni pada wa siwaju ẹrí, lati fi pamọ́ fun àmi fun awọn ọlọ̀tẹ nì; ki iwọ ki o si gbà kikùn wọn kuro lọdọ mi patapata ki nwọn ki o má ba kú.
11 Mose si ṣe bẹ̃: bi OLUWA ti fi aṣẹ fun u, bẹ̃li o ṣe.
12 Awọn ọmọ Israeli si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, awa kú, awa gbé, gbogbo wa gbé.
13 Ẹnikẹni ti o ba sunmọ agọ́ OLUWA yio kú: awa o ha fi kikú run bi?