1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
2 Eyi ni ìlana ofin, ti OLUWA palaṣẹ, wipe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o mú ẹgbọrọ abomalu pupa kan tọ̀ ọ wá, alailabawọ́n, ati alailabùku, ati lara eyiti a kò ti dì àjaga mọ́:
3 Ki ẹnyin si fi i fun Eleasari alufa, ki on ki o mú u jade lọ sẹhin ibudó, ki ẹnikan ki o si pa a niwaju rẹ̀:
4 Ki Eleasari alufa, ki o fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, ki o si fi ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n iwaju agọ́ ajọ ni ìgba meje.
5 Ki ẹnikan ki o si sun ẹgbọrọ abomalu na li oju rẹ̀; awọ rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati ẹ̀jẹ rẹ̀, pẹlu igbẹ́ rẹ̀, ni ki o sun:
6 Ki alufa na ki o mú igi opepe, ati hissopu, ati ododó, ki o si jù u sãrin ẹgbọrọ abomalu ti a nsun.
7 Nigbana ni ki alufa na ki o fọ̀ ãṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin na ki o si wá si ibudó, ki alufa na ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
8 Ki ẹniti o sun u ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀ ninu omi, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
9 Ki ọkunrin kan ti o mọ́ ki o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na, ki o si kó o jọ si ibi kan ti o mọ́ lẹhin ibudó, ki a si pa a mọ́ fun ijọ awọn ọmọ Israeli fun omi ìyasapakan: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.
10 Ki ẹniti o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: yio si jẹ́ ilana titilai, fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn.
11 Ẹniti o ba fọwọkàn okú ẹnikan ki o jẹ́ alaimọ ni ijọ́ meje.
12 Ki oluwarẹ̀ ki o fi i wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́ ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje yio di mimọ́: ṣugbọn bi kò ba wẹ̀ ara rẹ̀ ni ijọ́ kẹta, njẹ ni ijọ́ keje ki yio di mimọ́.
13 Ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn okú ẹnikan ti o kú, ti kò si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, o bà agọ́ OLUWA jẹ́; ọkàn na li a o si ke kuro ninu Israeli: nitoriti a kò wọ́n omi ìyasapakan si i lara, alaimọ́ li o jẹ̀; aimọ́ rẹ̀ mbẹ lara rẹ̀ sibẹ̀,
14 Eyi li ofin na, nigbati enia kan ba kú ninu agọ́ kan: gbogbo ẹniti o wọ̀ inu agọ́ na, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu agọ́ na, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje.
15 Ati ohun-èlo gbogbo ti o ṣi silẹ, ti kò ní ideri lori rẹ̀, alaimọ́ ni.
16 Ẹnikẹni ti o ba si fọwọkàn ẹnikan ti a fi idà pa ni gbangba igbẹ́, tabi okú kan, tabi egungun ẹnikan, tabi isà-okú, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje.
17 Ati fun ẹni aimọ́ kan ki nwọn ki o mú ninu ẽru sisun ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì, ki a si bù omi ti nṣàn si i ninu ohun-èlo kan:
18 Ki ẹnikan ti o mọ́ ki o si mú hissopu, ki o si tẹ̀ ẹ bọ̀ inu omi na, ki o si fi i wọ́n agọ́ na, ati ohun-èlo gbogbo, ati sara awọn enia ti o wá nibẹ̀, ati sara ẹniti o fọwọkàn egungun kan, tabi ẹnikan ti a pa, tabi ẹnikan ti o kú, tabi isà-okú:
19 Ki ẹniti o mọ́ na ki o si bùwọ́n alaimọ́ na ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje: ati ni ijọ́ keje ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́; ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omì, yio si di mimọ́ li aṣalẹ.
20 Ṣugbọn ẹniti o ba jẹ́ alaimọ́, ti kò ba wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ, nitoriti o bà ibi-mimọ́ OLUWA jẹ́: a kò si ta omi ìyasapakan si i lara; alaimọ́ li on.
21 Yio si ma jẹ́ ìlana lailai fun wọn, pe ẹniti o ba bú omi ìyasapakan wọ́n ẹni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀; ati ẹniti o si fọwọkàn omi ìyasapakan na yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
22 Ati ohunkohun ti ẹni aimọ́ na ba si farakàn, yio jẹ́ alaimọ́; ọkàn ti o ba si farakàn a, yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.