1 NJẸ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ní ọ̀pọlọpọ ohunọ̀sin: nwọn si ri ilẹ Jaseri, ati ilẹ Gileadi, si kiyesi i, ibẹ̀ na, ibi ohunọ̀sin ni;
2 Awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni si wá, nwọn si sọ fun Mose, ati fun Eleasari alufa ati fun awọn olori ijọ pe,
3 Atarotu, ati Diboni, ati Jaseri, ati Nimra, ati Heṣboni, ati Eleale, ati Ṣebamu, ati Nebo, ati Beoni.
4 Ilẹ na ti OLUWA ti kọlù niwaju ijọ Israeli, ilẹ ohunọ̀sin ni, awa iranṣẹ rẹ si ní ohunọ̀sin.
5 Nwọn si wipe, Bi awa ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, jẹ ki a fi ilẹ yi fun awọn iranṣẹ rẹ fun ilẹ-iní; ki o má si ṣe mú wa gòke Jordani lọ.
6 Mose si wi fun awọn ọmọ Gadi ati fun awọn ọmọ Reubeni pe, Awọn arakunrin nyin yio ha lọ si ogun, ki ẹnyin ki o si joko nihinyi?
7 Ẽṣe ti ẹnyin fi ntán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju ati rekọja lọ sinu ilẹ ti OLUWA fi fun wọn?
8 Bẹ̃li awọn baba nyin ṣe, nigbati mo rán wọn lati Kadeṣi-barnea lọ lati wò ilẹ na.
9 Nitoripe nigbati nwọn gòke lọ dé afonifoji Eṣkolu, ti nwọn si ri ilẹ na, nwọn tán ọkàn awọn ọmọ Israeli niyanju, ki nwọn ki o má le lọ sinu ilẹ ti OLUWA ti fi fun wọn.
10 Ibinu Ọlọrun si rú si wọn nigbana, o si bura, wipe,
11 Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti o gòke lati Egipti wá, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ki yio ri ilẹ na ti mo ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu: nitoriti nwọn kò tẹle mi lẹhin patapata.
12 Bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne ọmọ Kenissi, ati Joṣua ọmọ Nuni: nitoripe awọn li o tẹle OLUWA lẹhin patapata.
13 Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si mu wọn rìn kiri li aginjù li ogoji ọdún, titi gbogbo iran na, ti o ṣe buburu li oju OLUWA fi run.
14 Si kiyesi i, ẹnyin dide ni ipò baba nyin, iran ẹ̀lẹṣẹ, lati mu ibinu gbigbona OLUWA pọ̀ si i si Israeli.
15 Nitoripe bi ẹnyin ba yipada kuro lẹhin rẹ̀, on o si tun fi wọn silẹ li aginjù; ẹnyin o si run gbogbo awọn enia yi.
16 Nwọn si sunmọ ọ wipe, Awa o kọ́ ile-ẹran nihinyi fun ohunọ̀sin wa, ati ilu fun awọn ọmọ wẹ́wẹ wa:
17 Ṣugbọn awa tikala wa yio di ihamọra wa giri, niwaju awọn ọmọ Israeli, titi awa o fi mú wọn dé ipò wọn: awọn ọmọ wẹ́wẹ wa yio si ma gbé inu ilu olodi nitori awọn ara ilẹ na.
18 Awa ki yio pada bọ̀ si ile wa, titi olukuluku awọn ọmọ Israeli yio fi ní ilẹ-iní rẹ̀.
19 Nitoripe awa ki yio ní ilẹ-iní pẹlu wọn ni ìha ọhún Jordani, tabi niwaju: nitoriti awa ní ilẹ-iní wa ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla õrùn.
20 Mose si wi fun wọn pe, Bi ẹnyin o ba ṣe eyi; bi ẹnyin o ba di ihamọra niwaju OLUWA lọ si ogun,
21 Bi gbogbo nyin yio ba gòke Jordani ni ihamora niwaju OLUWA, titi yio fi lé awọn ọtá rẹ̀ kuro niwaju rẹ̀,
22 Ti a o si fi ṣẹ́ ilẹ na niwaju OLUWA: lẹhin na li ẹnyin o pada, ẹnyin o si jẹ́ àlailẹṣẹ niwaju OLUWA, ati niwaju Israeli; ilẹ yi yio si ma jẹ́ iní nyin niwaju OLUWA.
23 Ṣugbọn bi ẹnyin ki yio ba ṣe bẹ̃, kiyesi i, ẹnyin dẹ̀ṣẹ si OLUWA, ki o si dá nyin loju pe, ẹ̀ṣẹ nyin yio fi nyin hàn.
24 Ẹ kọ́ ilu fun awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ati agbo fun agutan nyin; ki ẹ si ṣe eyiti o ti ẹnu nyin jade wa.
25 Awọn ọmọ Gadi, ati awọn Reubeni si sọ fun Mose pe, Awọn iranṣẹ rẹ yio ṣe bi oluwa mi ti fi aṣẹ lelẹ.
26 Awọn ọmọ wẹ́wẹ wa, ati awọn aya wa, agbo-ẹran wa, ati gbogbo ohunọsìn wa yio wà nibẹ̀ ni ilu Gileadi:
27 Ṣugbọn awọn iranṣẹ rẹ yio gòke odò, olukuluku ni ihamọra ogun, niwaju OLUWA lati jà, bi oluwa mi ti wi.
28 Mose si paṣẹ fun Eleasari alufa, ati fun Joṣua ọmọ Nuni, ati fun awọn olori ile baba awọn ẹ̀ya ọmọ Israeli, nipa ti wọn.
29 Mose si wi fun wọn pe, Bi awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni yio ba bá nyin gòke Jordani lọ, olukuluku ni ihamọra fun ogun, niwaju OLUWA, ti a si ṣẹ́ ilẹ na niwaju nyin; njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ Gileadi fun wọn ni iní:
30 Ṣugbọn bi nwọn kò ba fẹ́ ba nyin gòke odò ni ihamọra, njẹ ki nwọn ki o ní iní lãrin nyin ni ilẹ Kenaani.
31 Ati awọn ọmọ Gadi ati awọn ọmọ Reubeni dahùn, wipe, Bi OLUWA ti wi fun awọn iranṣẹ rẹ, bẹ̃li awa o ṣe.
32 Awa o gòke lọ ni ihamọra niwaju OLUWA si ilẹ Kenaani, ki iní wa ni ìha ihin Jordani ki o le jẹ́ ti wa.
33 Mose si fi ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ati ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani fun wọn, ani fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse ọmọ Josefu, ilẹ na, pẹlu ilu rẹ̀ li àgbegbe rẹ̀, ani ilu ilẹ na yiká.
34 Awọn ọmọ Gadi si kọ́ Didoni, ati Atarotu, ati Aroeri;
35 Ati Atrotu-ṣofani, ati Jaseri, ati Jogbeha;
36 Ati Beti-nimra, ati Beti-harani, ilu olodi, ati agbo fun agutan.
37 Awọn ọmọ Reubeni si kọ́ Heṣboni, ati Eleale, ati Kiriataimu.
38 Ati Nebo, ati Baali-meoni, (nwọn pàrọ orukọ wọn,) ati Sibma: nwọn si sọ ilu ti nwọn kọ́ li orukọ miran.
39 Awọn ọmọ Makiri ọmọ Manase si lọ si Gileadi, nwọn si gbà a, nwọn si lé awọn ọmọ Amori ti o wà ninu rẹ̀.
40 Mose si fi Gileadi fun Makiri ọmọ Manase; o si joko ninu rẹ̀.
41 Jairi ọmọ Manasse, si lọ, o si gbà awọn ilu wọn, o si sọ wọn ni Haffotu-jairi.
42 Noba si lọ, o si gbà Kenati, ati awọn ileto rẹ̀, o si sọ ọ ni Noba, nipa orukọ ara rẹ̀.