Num 13 YCE

Mose Rán Amí lọ sí Ilẹ̀ Kenaani

1 OLUWA si sọ fun Mose pe,

2 Rán enia, ki nwọn ki o si ṣe amí ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli: ọkunrin kan ni ki ẹnyin ki o rán ninu ẹ̀ya awọn baba wọn, ki olukuluku ki o jẹ́ ijoye ninu wọn.

3 Mose si rán wọn lati ijù Parani lọ, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA: gbogbo awọn ọkunrin na jẹ́ olori awọn ọmọ Israeli.

4 Orukọ wọn si ni wọnyi: ninu ẹ̀ya Reubeni, Ṣammua ọmọ Sakuru.

5 Ninu ẹ̀ya Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori.

6 Ninu ẹ̀ya Juda, Kalebu ọmọ Jefunne.

7 Ninu ẹ̀ya Issakari, Igali ọmọ Josefu.

8 Ninu ẹ̀ya Efraimu, Oṣea ọmọ Nuni.

9 Ninu ẹ̀ya Benjamini, Palti ọmọ Rafu.

10 Ninu ẹ̀ya Sebuluni, Gaddieli ọmọ Sodi.

11 Ninu ẹ̀ya Josefu, eyinì ni, ninu ẹ̀ya Manasse, Gadi ọmọ Susi.

12 Ninu ẹ̀ya Dani, Ammieli ọmọ Gemalli.

13 Ninu ẹ̀ya Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli.

14 Ninu ẹ̀ya Naftali, Nabi ọmọ Fofsi.

15 Ninu ẹ̀ya Gaddi, Geueli ọmọ Maki.

16 Wọnyi li orukọ awọn ọkunrin na, ti Mose rán lati lọ ṣe amí ilẹ na. Mose si sọ Oṣea ọmọ Nuni ni Joṣua.

17 Mose si rán wọn lọ ṣe amí ilẹ Kenaani, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbà ọ̀na ìha gusù yi, ki ẹ sì lọ sori òke nì.

18 Ki ẹnyin si wò ilẹ na, bi o ti ri; ati awọn enia ti ngbé inu rẹ̀, bi nwọn ṣe alagbara tabi alailagbara, bi diẹ ni nwọn, tabi pupọ̀;

19 Ati bi ilẹ na ti nwọn ngbé ti ri, bi didara ni bi buburu ni; ati bi ilu ti nwọn ngbé ti ri, bi ninu agọ́ ni, tabi ninu ilu odi;

20 Ati bi ilẹ na ti ri, bi ẹlẹtu ni tabi bi aṣalẹ̀, bi igi ba mbẹ ninu rẹ̀, tabi kò sí. Ki ẹnyin ki o si mu ọkàn le, ki ẹnyin si mú ninu eso ilẹ na wá. Njẹ ìgba na jẹ́ akokò pipọn akọ́so àjara.

21 Bẹ̃ni nwọn gòke lọ, nwọn si ṣe amí ilẹ na lati ijù Sini lọ dé Rehobu, ati lọ si Hamati.

22 Nwọn si ti ìha gusù gòke lọ, nwọn si dé Hebroni; nibiti Ahimani, Ṣeṣai, ati Talmai, awọn ọmọ Anaki gbé wà. (A ti tẹ̀ Hebroni dò li ọdún meje ṣaju Soani ni Egipti.)

23 Nwọn si dé odò Eṣkolu, nwọn si rẹ́ ọwọ́ àjara kan, ti on ti ìdi eso-àjara kan lati ibẹ̀ wá, awọn enia meji si fi ọpá rù u; nwọn si mú ninu eso-pomegranate, ati ti ọpọtọ́ wá.

24 Nwọn si sọ ibẹ̀ na ni odò Eṣkolu, nitori ìdi-eso ti awọn ọmọ Israeli rẹ́ lati ibẹ̀ wá.

25 Nwọn si pada ni rirìn ilẹ na wò lẹhin ogoji ọjọ́.

26 Nwọn si lọ nwọn tọ̀ Mose wá, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ni ijù Parani, ni Kadeṣi; nwọn si mú ọ̀rọ pada tọ̀ wọn wá, ati gbogbo ijọ, nwọn si fi eso ilẹ na hàn wọn.

27 Nwọn si rò fun u, nwọn si wipe, Awa dé ilẹ na nibiti iwọ gbé rán wa lọ, nitõtọ li o nṣàn fun warà ati fun oyin; eyi si li eso rẹ̀.

28 Ṣugbọn alagbara ni awọn enia ti ngbé inu ilẹ na, ilu olodi si ni ilu wọn, nwọn tobi gidigidi: ati pẹlupẹlu awa ri awọn ọmọ Anaki nibẹ̀.

29 Awọn ara Amaleki si ngbé ilẹ ìha gusù: ati awọn Hitti, ati awọn Jebusi, ati awọn Amori, ngbé ori-òke: awọn ara Kenaani si ngbé ẹba okun, ati ni àgbegbe Jordani.

30 Kalebu si pa awọn enia lẹnu mọ́ niwaju Mose, o si wipe, Ẹ jẹ ki a gòke lọ lẹ̃kan, ki a si gbà a; nitoripe awa le ṣẹ́ ẹ.

31 Ṣugbọn awọn ọkunrin ti o bá a gòke lọ wipe, Awa kò le gòke tọ̀ awọn enia na lọ; nitoriti nwọn lagbara jù wa lọ.

32 Nwọn si mú ìhin buburu ti ilẹ na, ti nwọn ti ṣe amí wá fun awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ ti imu awọn enia rẹ̀ jẹ ni; ati gbogbo enia ti awa ri ninu rẹ̀ jẹ́ enia ti o ṣigbọnlẹ.

33 Ati nibẹ̀ li awa gbé ri awọn omirán, awọn ọmọ Anaki ti o ti inu awọn omirán wá: awa si dabi ẹlẹnga li oju ara wa, bẹ̃li awa si ri li oju wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36