Num 29 YCE

Ẹbọ Àjọ̀dún Ọdún Titun

1 ATI li oṣù keje, li ọjọ́ kini oṣù na ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: ọjọ́ ifunpe ni fun nyin.

2 Ki ẹnyin ki o si fi ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku ru ẹbọ sisun fun õrùn didùn si OLUWA:

3 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan,

4 Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje:

5 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, lati ṣètutu fun nyin;

6 Pẹlu ẹbọ sisun oṣù, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn, gẹgẹ bi ìlana wọn, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.

Ẹbọ Ọjọ́ Ètùtù

7 Ki ẹnyin ki o si ní apejọ mimọ́ ni ijọ́ kẹwa oṣù keje na yi; ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan:

8 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun si OLUWA fun õrùn didùn; ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan; ki nwọn ki o si jẹ́ alailabùku fun nyin:

9 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji ọsuwọn fun àgbo kan,

10 Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje:

11 Obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ètutu, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn.

12 Ati ni ijọ́ kẹdogun oṣù keje, ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan, ki ẹnyin ki o si ṣe ajọ fun OLUWA ni ijọ́ meje:

13 Ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ sisun kan, ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu mẹtala, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan; ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku:

14 Ati ẹbọ ohun-jijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, bẹ̃ni fun akọmalu mẹtẹtala, idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan, bẹ̃ni fun àgbo mejeji,

15 Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mẹrẹrinla:

16 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.

17 Ati ni ijọ́ keji ni ki ẹnyin ki o fi ẹgbọrọ akọmalu mejila, àgbo meji, ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku rubọ:

18 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:

19 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn.

20 Ati ni ijọ́ kẹta akọmalu mọkanla, àgbo meji, akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku;

21 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:

22 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.

23 Ati ni ijọ́ kẹrin akọmalu mẹwa, àgbo meji, ati ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku:

24 Ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:

25 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.

26 Ati ni ijọ́ karun akọmalu mẹsan, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku:

27 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:

28 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.

29 Ati ni ijọ́ kẹfa akọmalu mẹjọ, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku:

30 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:

31 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.

32 Ati ni ijọ́ keje akọmalu meje, àgbo meji, ati akọ ọdọ-agutan mẹrinla ọlọdún kan alailabùku:

33 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:

34 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.

35 Ni ijọ́ kẹjọ ki ẹnyin ki o ní ajọ ti o ni ironu: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan.

36 Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA: akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku:

37 Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn fun akọmalu, fun àgbo, ati fun ọdọ-agutan, ki o jẹ́ bi iye wọn, gẹgẹ bi ìlana na:

38 Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.

39 Ẹbọ wọnyi ni ki ẹnyin ki o ru si OLUWA li ajọ nyin, pẹlu ẹjẹ́ nyin, ati ẹbọ ọrẹ-atinuwa nyin, fun ẹbọ sisun nyin, ati fun ẹbọ ohunjijẹ nyin, ati fun ẹbọ ohun mimu nyin, ati fun ẹbọ alafia nyin.

40 Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ fun Mose.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36