1 OLUWA si sọ fun Mose pe,
2 Iwọ ṣe ipè fadakà meji; iṣẹ́-ọnà lilù ni ki o ṣe wọn: iwọ o si ma fi wọn pè ajọ, iwọ o si ma fi wọn ṣí ibudó.
3 Nigbati nwọn ba fun wọn, ki gbogbo ijọ ki o pé sọdọ rẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
4 Bi o ba ṣepe ipè kan ni nwọn fun, nigbana ni ki awọn ijoye, olori ẹgbẹgbẹrun enia Israeli, ki o pejọ sọdọ rẹ.
5 Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha ìla-õrùn ki o ṣí siwaju.
6 Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri nigba keji, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha gusù ki o ṣì siwaju: ki nwọn ki o si fun ipè idagiri ṣíṣi wọn.
7 Ṣugbọn nigbati a o ba pè ijọ pọ̀, ki ẹ fun ipè, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ fun ti idagiri.
8 Awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, ni ki o si fun ipè na; ki nwọn ki o si ma ṣe ìlana lailai fun nyin ni iran-iran nyin.
9 Bi ẹnyin ba si lọ si ogun ni ilẹ nyin lọ ipade awọn ọtá ti nni nyin lara, nigbana ni ki ẹnyin ki o fi ipè fun idagiri; a o si ranti nyin niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, a o si gbà nyin lọwọ awọn ọtá nyin.
10 Li ọjọ̀ ayọ̀ nyin pẹlu, ati li ajọ nyin, ati ni ìbẹrẹ oṣù nyin, ni ki ẹnyin ki o fun ipè sori ẹbọ sisun nyin, ati sori ẹbọ ti ẹbọ alafia nyin; ki nwọn ki o le ma ṣe iranti fun nyin niwaju Ọlọrun nyin: Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin.
11 O si ṣe li ogun ọjọ́ oṣù keji, li ọdún keji, ni awọsanma ká soke kuro lori agọ́ ẹrí.
12 Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati ijù Sinai; awọsanma na si duro ni ijù Parani.
13 Nwọn si bẹ̀rẹsi iṣí gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.
14 Ọpágun ibudó awọn ọmọ Juda si kọ́ ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Naṣoni ọmọ Amminadabu.
15 Olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari si ni Netaneli ọmọ Suari.
16 Olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Sebuluni ni Eliabu ọmọ Heloni.
17 A si tú agọ́ na palẹ; awọn ọmọ Gerṣoni, ati awọn ọmọ Merari ti nrù agọ́ si ṣí.
18 Ọpágun ibudó Reubeni si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: Elisuri ọmọ Ṣedeuri si li olori ogun rẹ̀.
19 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni ni Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai
20 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Gadi ni Eliasafu ọmọ Deueli.
21 Awọn ọmọ Kohati ti nrù ohun mimọ́ si ṣí: awọn ti iṣaju a si ma gbé agọ́ ró dè atidé wọn.
22 Ọpágun ibudó awọn ọmọ Efraimu si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu si li olori ogun rẹ̀.
23 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse ni Gamalieli ọmọ Pedasuri.
24 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini ni Abidani ọmọ Gideoni.
25 Ọpágun ibudó awọn ọmọ Dani, ti o kẹhin gbogbo ibudó, si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.
26 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri ni Pagieli ọmọ Okrani.
27 Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali ni Ahira ọmọ Enani.
28 Bayi ni ìrin awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ogun wọn; nwọn si ṣí.
29 Mose si wi fun Hobabu, ọmọ Ragueli ara Midiani, ana Mose pe, Awa nṣí lọ si ibi ti OLUWA ti wi pe, Emi o fi i fun nyin: wá ba wa lọ, awa o ṣe ọ li ore: nitoripe OLUWA sọ̀rọ rere nipa Israeli.
30 On si wi fun u pe, Emi ki yio lọ; ṣugbọn emi o pada lọ si ilẹ mi, ati sọdọ ará mi.
31 O si wipe, Máṣe fi wa silẹ, emi bẹ̀ ọ; iwọ sà mọ̀ pe ni ijù li awa dó si, iwọ o si ma ṣe oju fun wa.
32 Yio si ṣe, bi iwọ ba bá wa lọ, yio si ṣe, pe, orekore ti OLUWA ba ṣe fun wa, on na li awa o ṣe fun ọ.
33 Nwọn si ṣí kuro ni òke OLUWA ni ìrin ijọ́ mẹta: apoti majẹmu OLUWA si ṣiwaju wọn ni ìrin ijọ́ mẹta, lati wá ibi isimi fun wọn.
34 Awọsanma OLUWA mbẹ lori wọn li ọsán, nigbati nwọn ba ṣí kuro ninu ibudó.
35 O si ṣe, nigbati apoti ẹrí ba ṣí siwaju, Mose a si wipe, Dide, OLUWA, ki a si tú awọn ọtá rẹ ká; ki awọn ti o korira rẹ ki o si salọ kuro niwaju rẹ.
36 Nigbati o ba si simi, on a wipe, Pada, OLUWA, sọdọ ẹgbẹgbarun awọn enia Israeli.