Num 31 YCE

Wọ́n Dojú Ogun Mímọ́ kọ Midiani

1 OLUWA si sọ fun Mose pe,

2 Gbẹsan awọn ọmọ Israeli lara awọn ara Midiani: lẹhin eyinì ni a o kó ọ jọ pẹlu awọn enia rẹ.

3 Mose si sọ fun awọn enia na pe, Ki ninu nyin ki o hamọra ogun, ki nwọn ki o si tọ̀ awọn ara Midiani lọ, ki nwọn ki o si gbẹsan OLUWA lara Midiani.

4 Ninu ẹ̀ya kọkan ẹgbẹrun enia, ni gbogbo ẹ̀ya Israeli, ni ki ẹnyin ki o rán lọ si ogun na.

5 Bẹ̃ni nwọn si yàn ninu awọn ẹgbẹgbẹrun enia Israeli, ẹgbẹrun enia ninu ẹ̀ya kọkan, ẹgba mẹfa enia ti o hamọra ogun.

6 Mose si rán wọn lọ si ogun na, ẹgbẹrun enia ninu ẹ̀ya kọkan, awọn ati Finehasi ọmọ Eleasari alufa si ogun na, ti on ti ohunèlo ibi-mimọ́, ati ipè wọnni li ọwọ́ rẹ̀ lati fun.

7 Nwón si bá awọn ara Midiani jà, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose; nwọn si pa gbogbo awọn ọkunrin.

8 Nwọn si pa awọn ọba Midiani, pẹlu awọn iyokù ti a pa; eyinì ni Efi, ati Rekemu, ati Suru, ati Huri, ati Reba, ọba Midiani marun: Balaamu ọmọ Beoru ni nwọn si fi idà pa.

9 Awọn ọmọ Israeli si mú gbogbo awọn obinrin Midiani ni igbẹsin, ati awọn ọmọ kekere wọn, nwọn si kó gbogbo ohunọ̀sin wọn, ati gbogbo agboẹran wọn, ati gbogbo ẹrù wọn.

10 Nwọn si fi iná kun gbogbo ilu wọn ninu eyiti nwọn ngbé, ati gbogbo ibudó wọn.

11 Nwọn si kó gbogbo ikogun wọn, ati gbogbo ohun-iní, ati enia ati ẹran.

12 Nwọn si kó igbẹsin, ati ohun-iní, ati ikogun na wá sọdọ Mose, ati Eleasari alufa, ati sọdọ ijọ awọn ọmọ Israeli, si ibudó ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, ti mbẹ lẹba Jordani leti Jeriko.

Àwọn Ọmọ Ogun Pada Wálé

13 Ati Mose, ati Eleasari alufa, ati gbogbo awọn olori ijọ, jade lọ ipade wọn lẹhin ibudó.

14 Mose si binu si awọn olori ogun na, pẹlu awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati balogun ọrọrún, ti o ti ogun na bọ̀.

15 Mose si wi fun wọn pe, Ẹ da gbogbo awọn obinrin si?

16 Kiyesi i, nipaṣe ọ̀rọ Balaamu awọn wọnyi li o mu awọn ọmọ Israeli dẹ̀ṣẹ si OLUWA niti ọ̀ran Peori, ti àrun si fi wà ninu ijọ OLUWA.

17 Njẹ nitorina, ẹ pa gbogbo ọkunrin ninu awọn ọmọ wẹ́wẹ, ki ẹ si pa gbogbo awọn obinrin ti o ti mọ̀ ọkunrin nipa ibá dapọ̀.

18 Ṣugbọn gbogbo awọn ọmọbinrin kekeké ti nwọn kò mọ̀ ọkunrin nipa ibá dapọ̀, ni ki ẹnyin dasi fun ara nyin.

19 Ki ẹnyin ki o si duro lẹhin ibudó ni ijọ meje: ẹnikẹni ti o ba pa enia, ati ẹnikẹni ti o ba farakàn ẹniti a pa, ki ẹnyin si wẹ̀ ara nyin mọ́, ati ara awọn igbẹsin nyin ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje.

20 Ki ẹnyin si fọ̀ gbogbo aṣọ nyin mọ́, ati gbogbo ohun ti a fi awọ ṣe, ati ohun gbogbo iṣẹ irun ewurẹ, ati ohun gbogbo ti a fi igi ṣe.

21 Eleasari alufa si wi fun awọn ologun ti nwọn lọ si ogun na pe, Eyi ni ilana ofin ti OLUWA filelẹ li aṣẹ fun Mose.

22 Kìki wurà, ati fadakà, ati idẹ ati irin, ati tanganran, ati ojé,

23 Gbogbo ohun ti o le kọja ninu iná, ni ki ẹnyin ki o mu là iná já yio si di mimọ́; ṣugbọn a o fi omi ìyasapakan wẹ̀ ẹ mọ́: ati gbogbo ohun ti kò le kọja ninu iná ni ki a mu là inu omi.

24 Ki ẹnyin ki o si fọ̀ aṣọ nyin ni ijọ́ keje, ẹnyin o si di mimọ́, lẹhin eyinì li ẹnyin o si wá sinu ibudó.

Pípín Ìkógun

25 OLUWA si sọ fun Mose pe,

26 Kà iye ikogun ti a kó, ti enia ati ti ẹran, iwọ ati Eleasari alufa, ati awọn olori ile baba ijọ:

27 Ki o si pín ikogun na si ipa meji; lãrin awọn ologun, ti o jade lọ si ogun na, ati lãrin gbogbo ijọ.

28 Ki o si gbà ohun idá ti OLUWA lọwọ awọn ologun ti nwọn jade lọ si ogun na: ọkan ninu ẹdẹgbẹta, ninu awọn enia, ati ninu malu, ati ninu kẹtẹkẹtẹ, ati ninu agbo-ẹran:

29 Gbà a ninu àbọ ti wọn, ki o si fi i fun Eleasari alufa, fun ẹbọ igbesọsoke OLUWA.

30 Ati ninu àbọ ti iṣe ti awọn ọmọ Israeli, ki iwọ ki o si gbà ipín kan ninu ãdọta, ninu enia, ninu malu, ninu kẹtẹkẹtẹ, ati ninu agbo-ẹran, ninu onirũru ẹran, ki o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, ti nṣe itọju agọ́ OLUWA.

31 Ati Mose ati Eleasari alufa si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

32 Ati ikogun ti o kù ninu ohun-iní ti awọn ologun kó, o jẹ́ ọkẹ mẹrinlelọgbọ̀n o din ẹgbẹdọgbọ̀n agutan,

33 Ẹgba mẹrindilogoji malu,

34 Ọkẹ mẹta o le ẹgbẹrun kẹtẹkẹtẹ,

35 Ati enia ninu awọn obinrin ti kò mọ̀ ọkunrin nipa ibá dàpọ, gbogbo wọn jẹ́ ẹgba mẹrindilogun.

36 Ati àbọ ti iṣe ipín ti awọn ti o jade lọ si ogun, o jẹ́ ẹgba mejidilãdọsan o le ẹdẹgbẹjọ agutan ni iye:

37 Idá ti OLUWA ninu agutan wọnni jẹ́ ẹdẹgbẹrin o din mẹdọgbọ̀n.

38 Ati malu jẹ́ ẹgba mejidilogun; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ mejilelãdọrin.

39 Kẹtẹkẹtẹ si jẹ́ ẹgba mẹdogun o le ẹdẹgbẹta; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ́ ọgọta o le ọkan.

40 Awọn enia si jẹ́ ẹgba mẹjọ; ninu eyiti idá ti OLUWA jẹ́ ọgbọ̀n o le meji.

41 Mose si fi idá ti ẹbọ igbesọsoke OLUWA fun Eleasari alufa, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

42 Ati ninu àbọ ti awọn ọmọ Israeli, ti Mose pín kuro ninu ti awọn ọkunrin ti o jagun na,

43 (Njẹ àbọ ti ijọ jẹ́ ẹgba mejidilãdọsan o le ẹdẹgbẹjọ agutan,

44 Ati ẹgba mejidilogun malu.

45 Ati ẹgba mẹdogun o le ẹdẹgbẹta kẹtẹkẹtẹ.

46 Ati ẹgba mẹjọ enia;)

47 Ani ninu àbọ ti awọn ọmọ Israeli, Mose mú ipín kan ninu ãdọta, ati ti enia ati ti ẹran, o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, ti nṣe itọju agọ́ OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

48 Ati awọn olori ti o wà lori ẹgbẹgbẹrun ogun na, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati awọn balogun ọrọrún, wá sọdọ Mose:

49 Nwọn si wi fun Mose pe, Awọn iranṣẹ rẹ ti kà iye awọn ologun, ti mbẹ ni itọju wa, ọkunrin kan ninu wa kò si din.

50 Nitorina li awa ṣe mú ọrẹ-ebọ wá fun OLUWA, ohunkohun ti olukuluku ri, ohun ọ̀ṣọ wurà, ẹ̀wọn, ati jufù, ati oruka-àmi, ati oruka-etí, ati ìlẹkẹ, lati fi ṣètutu fun ọkàn wa niwaju OLUWA.

51 Mose ati Eleasari alufa si gbà wurà na lọwọ wọn, ani gbogbo ohun-iṣẹ ọsọ́.

52 Ati gbogbo wurà ẹbọ igbesọsoke ti nwọn múwa fun OLUWA, lati ọdọ awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati lati ọdọ awọn balogun ọrọrún, o jẹ́ ẹgba mẹjọ o le ẹdẹgbẹrin o le ãdọta ṣekeli.

53 (Nitoripe awọn ologun ti kó ẹrù, olukuluku fun ara rẹ̀.)

54 Mose ati Eleasari alufa si gbà wurà na lọwọ awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati lọwọ awọn balogun ọrọrún nwọn si mú u wá sinu agọ́ ajọ, ni iranti fun awọn ọmọ Israeli niwaju OLUWA.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36